Faith Adebọla
Ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Supreme Court, ti kede pe ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Karun-un, yii, lawọn yoo gbe idajọ kalẹ lori ẹjọ abajade esi idibo sipo gomina ipinlẹ Ọṣun, to ti n ja ranyin lati oṣu diẹ sẹyin, kootu naa ni awọn ti ṣetan lati fẹnu ọrọ yii jona wayi.
Ninu lẹta kan ti kootu naa fi ṣọwọ sawọn lọọya olujẹjọ ati olupẹjọ ni wọn ti sọ fun tọtun-tosi wọn pe ki kaluku wọn wọṣọ agbẹjọro rẹ, ki wọn si de wiigi wọn, ki wọn pade awọn adajọ ẹlẹni marun-un ti wọn ti ṣe atupalẹ ati atunyẹwo gbogbo atotonu ati idajọ to ti waye sẹyin lori ẹjọ naa, wọn ni ọjọ Tusidee tilẹ rẹ mọ tan yii lawọn maa gbe are falare, tawọn yoo si gbe ẹbi fẹlẹbi poo.
Ẹ oo ranti pe lati bii oṣu mẹjọ sẹyin ni igbẹjọ ti bẹrẹ lori ẹjọ kan ti gomina ana nipinlẹ Ọṣun, Alaaji Gboyega Isiaka Oyetọla ati ẹgbẹ oṣelu rẹ, All Progressives Congress (APC), pe ta ko esi idibo ati ijawe olubori Gomina ipinlẹ naa lọwọlọwọ, Sẹnetọ Ademọla Nurudeen Adeleke, ti ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP).
Lẹyin ti igbimọ onidaajọ to n gbọ awuyewuye to ba su yọ ninu eto idibo gomina, iyẹn igbimọ Tiribunal Ọṣun, ọhun kọkọ gbọ ẹjọ naa, wọn da Adeleke lẹbi, wọn loun kọ lo wọle sipo gomina, tori magomago ati adiju ibo waye lawọn ibudo idibo kan, nigba tawọn si yọ adiju ibo yii kuro lara ojulowo ibo, Oyetọla lo yege, tori ẹ, wọn ni ki ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC, tara ṣaṣa kede Oyetọla bii gomina aṣẹṣẹ dibo yan, ki wọn si gba iwe-ẹri ‘mo yege’ ti wọn ti fun Adeleke kuro lọwọ ẹ, ki wọn fun Oyetọla.
Amọ omi gbigbona o gbọdọ pẹ lẹnu, ọwọ ko si gbọdọ pẹ nisa akeeke ni Ademọla atawọn lọọya rẹ fi idajọ naa ṣe, kia ni wọn ti gba ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun lọ, wọn ni ki wọn kọkọ ba awọn da INEC lọwọ kọ na, lẹyin naa naa ni wọn pẹjọ ta ko idajọ Tribunal Ọṣun.
Ninu oṣu Kẹta, ọdun yii, ti ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun gbe idajọ wọn kalẹ, niṣe ni wọn wọgi le idajọ igbimọ to kọkọ gbọ ẹjọ ọhun, eyi to da Oyetọla lare, wọn ni ẹjọ ti wọn da ọhun ko daa, tori lakọọkọ na, ẹsẹ awọn adajọ naa ko pe lasiko idajọ, iwe esi idibo ti INEC si loun tun ko wa, wọn o tiẹ yẹ ẹ wo rara, tori ẹ, osuwọn idajọ naa ko pe, wọn ni ki Adeleke maa ba iṣejọba rẹ lọ.
Lọgan ni Oyetọla naa tun kede pe oun ko gba, o ni ile-ẹjọ ti ẹjọ maa n pẹkun si, ‘Supreme Court’, lo maa ba awọn da a, n ni wọn ba taari iwe ẹjọ ati igbẹjọ naa si wọn.
Ilẹkẹ ma ja sile, ilẹkẹ ma ja sita, ibi kan nilẹkẹ yoo ja si dandan. Ọjọ Tusidee ni gbogbo olugbe ipinlẹ Ọṣun atawọn ọmọ Naijiria n reti bayii, lati mọ ibi tẹjọ yoo fori sọ.