Ibo gomina ti yoo waye ni Satide l’Ondo, ta ni yoo wọle?

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Bi eto idibo sipo gomina to fẹẹ waye lopin ọsẹ ta a wa yii ṣe n sun mọle ni ipenija to n koju awọn oludije naa n peleke si i, bẹẹ ni ko sẹni to ti i le sọ ni pato iru ẹgbẹ oṣelu ti yoo jawe olubori ninu eto idibo naa.

Bo tilẹ jẹ pe awọn ẹgbẹ oṣelu bii mẹtadinlogun ni wọn fẹẹ kopa, sibẹ, ohun to da awọn eeyan ipinlẹ Ondo loju ni pe aarin awọn mẹta pere, iyẹn ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress (APC), People’s Democratic Party (PDP) ati Zenith Labour Party (ZLP) lo ṣee ṣe ki kinni ọhun fi si.

Awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu mẹtẹẹta yii ni wọn n leri leka, ti olukuluku wọn si gbagbọ pe oludije ti awọn fa kalẹ ni yoo jawe olubori ninu eto idibo naa, ọrọ yii si ti kuro ni ti ori ahọn lasan, gbogbo igbesẹ ti wọn ro pe o le ran awọn lọwọ lati rọwọ mu ninu eto idibo naa ni wọn n gbe.

Ẹkun idibo mẹta ni wọn pin ipinlẹ Ondo si, Ẹkun idibo Ariwa ninu eyi ta a ti ri ijọba ibilẹ Akoko mẹrẹẹrin, Ọwọ ati Ọsẹ, eyi ni ẹkun ti Gomina Rotimi Akeredolu, ẹni ti ẹgbẹ oṣelu APC tun fa kalẹ lati dije lẹẹkeji ti wa.

Ẹkun Aarin-Gbungbun ipinlẹ Ondo, nibi ti Eyitayọ Jẹgẹdẹ to jẹ oludije ẹgbẹ PDP ti wa, awọn ijọba ibilẹ mẹfa to wa labẹ ẹkun yii ni, Ariwa ati Guusu Akurẹ, Ila-Oorun ati Iwọ-Oorun Ondo, Idanre ati Ifẹdọrẹ.

Bakan naa la ri ẹkun Guusu ibi ti awọn ijọba ibilẹ bii, Ilẹ-Oluji/Oke-Igbo, Odigbo, Ilajẹ, Irele, Okitipupa ati Ẹsẹ-Odo wa, Ọmọ bibi ẹkun yii ni Igbakeji Gomina ipinlẹ Ondo,Ọnarebu Agboọla Ajayi, to jẹ oludije ẹgbẹ ZLP.

Ọdun mẹrin ni gomina alagbada akọkọ nipinlẹ Ondo, Oloogbe Adekunle Ajasin, to wa lati ẹkun Ariwa fi tukọ ijọba ipinlẹ Ondo, iyẹn lati ọdun 1979 si 1983, ẹkun yii kan naa ni Ologbe Adebayọ Adefarati to ṣakoso laarin ọdun 1999 si 2003 ti wa.

Oloogbe Oluṣẹgun Agagu to ṣejọba laarin ọdun 2003 si 2009 wa lati Ẹkun Guusu, Dokita Oluṣẹgun Mimiko to si wa lati ẹkun Aarin-Gbungbun ṣejọba ọdun mẹjọ gbako (2009-2017) nigba ti Arakunrin Rotimi Akeredolu to gba ijọba lọwọ rẹ wa lati ẹkun Ariwa.

Bo tilẹ jẹ pe ko sibi ti wọn ti n jokoo ṣe ipade lori ẹkun to yẹ ko dije dupo gomina ipinlẹ Ondo, sibẹ, ọrọ yii wa lara ohun tawọn oludije wọnyi atawọn alatilẹyin wọn maa n tẹnumọ ju lọ lati ta ko ara wọn lasiko ti wọn ba n polongo ibo.

Igbagbọ awọn ọmọ ẹgbẹ APC ni pe niwọn igba ti Ẹkun Aarin-Gbungbun ti lo ọdun mẹjọ tiwọn pe lori aleefa, ko sohun to yẹ ko di oludije awọn lọwọ lati lọ fun saa keji gẹgẹ bii gomina.

Wọn ni kawọn eeyan ẹkun Aarin-Gbungbun lọọ ni suuru titi di ọjọ mi-in ọjọ ire, nitori pe ọna wọn ṣi jin pupọ ki wọn too tun gbọ iro ipo gomina.

Lati fi bi wọn ṣe koriira Dokita Mimiko si han nigba to ṣi wa lori aleefa, Akeredolu ni ọgọọrọ awọn eeyan ẹkun Guusu (paapaa awọn ti wọn jẹ ọmọlẹyin Oloogbe Agagu) ṣatilẹyin fun lasiko eto idibo gomina to waye lọdun 2016.

Koda, pupọ ninu awọn alabaaṣisẹpọ gomina ana ọhun ni wọn kẹyin si i nigba naa latari bo ṣe yan Jẹgẹdẹ laayo gẹgẹ bii arọpo rẹ nigba naa dipo ko mu ọkan ninu wọn, Idi ree ti gbogbo wọn fi gbimọ-pọ pẹlu Jimoh Ibrahim, pẹlu agbara ijọba apapọ, lati yi Jẹgẹdẹ lagbo da sina.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ ninu iwadii ta a ṣe pe ki i ṣe pe o wu Ọnarebu Ajayi lati gbe apoti ta ko ọga rẹ ninu eto idibo to n bọ yii, awọn eeyan kan lati ẹkun Guusu ni wọn gbo o laya, ti wọn si fi dandan le e fun un lati dupo naa.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, wọn lo kọkọ wu Ajayi lati juwọ silẹ fun Jẹgẹdẹ latari ẹbẹ tawọn olori ẹgbẹ PDP kan n bẹ ẹ lẹyin to fidi rẹmi ninu eto idibo abẹle, ṣugbọn awọn eeyan rẹ ni wọn yari, ti wọn si ni dandan ni, o gbọdọ waa dije nitori pe Ẹkun awọn ni ipo gomina kan.

Ohun tawọn eeyan ẹkun Aarin-Gbungbun duro le lori ni tiwọn ni pe o to akoko to yẹ ki ọmọ bibi ilu Akurẹ naa de ipo gomina ipinlẹ Ondo lati bii ogoji ọdun o le ti wọn ti da ipinlẹ naa silẹ.

Lọwọlọwọ ba a ṣe n sọrọ yii, ẹkun idibo kọọkan lo duro wamuwamu lẹyin awọn eeyan wọn to n dije, awọn oludije wọnyi si gbagbọ pe lẹyin ọpọ ibo ti awọn ba ri lati ẹkun awọn, o di dandan ki awọn tun ri awọn ibo diẹdiẹ ja gba lati awọn Ẹkun yooku.

Idi ree ti ọkọọkan awọn oludije naa fi lọọ mu igbakeji lati Ẹkun mi-in to yatọ sibi ti wọn ti wa. Fun apẹẹrẹ, ọmọ Ẹkun Guusu ni Lucky Ayedatiwa ti Gomina Akeredolu fẹẹ lo bii igbakeji rẹ, ẹkun yii kan naa si ni Gboluga Ikuegboju ti wa to jẹ igbakeji Jẹgẹdẹ ti wa, nigba ti Gboye Adegbenro to n dije pẹlu Ọnarebu Ajayi wa lati ijọba ibilẹ Ifẹdọre, ni ẹkun Aarin-Gbungbun.

Ijọba ibilẹ Guusu Akurẹ ni ẹkun Aarin-Gbungbun ni pupọ ibo ti wọn n di nipinlẹ Ondo ti n wa, ibo to n wa lati ijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo lo tun tẹle e, nigba ti ibo awọn eeyan ijọba ibile Ilajẹ ṣe ẹkẹta wọn.

Ọsẹ to kọja ni Gomina Akeredolu sare san oṣu kan ninu owo oṣu meji to jẹ awọn oṣiṣẹ, ireti si wa pe o ṣee ṣe ko tun san omiiran fun wọn lọsẹ yii, lati wa ojurere wọn.

O han pe ẹgbẹ APC to n ṣejọba ti su pupọ awọn eeyan ipinlẹ Ondo nitori pe ilana ti gomina to wa lori oye fi n ṣejọba ko tẹ wọn lọrun. Diẹ ninu awọn nnkan to n bi awọn eeyan ninu si Akeredolu ni ti owo ile-iwe giga ipinlẹ Ondo to ṣe afikun rẹ, fifagi  le eto ilera ọfẹ, gbigbẹsẹ le owo ajẹmọnu awọn oṣiṣẹ ati yiyọ owo wọn ni iyọkuyọ lati igba to ti dori aleefa. Bakan naa ni ti akọlu igba gbogbo tawọn alatilẹyin rẹ n ṣe si awọn alatako lati bii oṣu diẹ sẹyin.

Igbagbọ awọn eeyan kan lori eto idibo to n bọ yii ni pe ko si bi awọn ẹgbẹ alatako ṣe fẹẹ fẹyin Gomina Akeredolu janlẹ ninu eto idibo naa nitori pe ijọba apapọ ko ni i fọwọ lẹran ki ipinlẹ Ondo tun bọ mọ wọn lọwọ lẹyin ti ipinlẹ Edo ti bọ sọwọ ẹgbẹ PDP.

Leave a Reply