Ibo ipinlẹ Edo: Godwin Obaseki wọle gedegbe

Aderounmu Kazeem

Idunnu lo ṣubu layọ fawọn ọmọ ẹgbe oṣelu PDP bi Godwin Obaseki ṣe jawe olubori ninu ibo gomina to waye nipinlẹ wọn.

Gomina Godwin Obaseki ti ẹgbẹ oṣelu PDP lo wọle o, ibo to si gbe e wọle le diẹ ni ẹgbẹrun lọna ọodunrun (308,125) nigba ti ẹgbẹ oṣelu APC ni tiẹ ni ibo to le ni ẹgbẹrun lọna okoolelugba (223,622).

Kaakiri orilẹ-ede yii lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu ọhun ti n jo ti wọn n yọ, nitori idije ibo to gbona janjan ni.

Ṣe ohun to fa sabaabi ẹ ni wahala to bẹ silẹ laarin Adams Oshiomhole ẹni to jẹ alaga ẹgbẹ ọhun tẹlẹ, bẹẹ lo tun jẹ pe oun gan-an lo mu Godwin Obaseki wa, to si polongo ibo fun un lọdun 2016 nigba ti Oshiomhole pari saa ẹ keji tan.

Bi ija buruku ti ṣe bẹ si wọn laarin niyen o, ti Obaseki si gba inu ẹgbẹ oṣelu PDP lọ. Bo ṣe fi ẹgbẹ APC silẹ lawon eeyan kan ṣe n woye wi pe, yoo ṣoro fun un lati pada di gomina nipinlẹ naa.

Ṣa o, ọrọ ti yi biri o, Godwin lo wọle o, bẹẹ lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ko si ri nnkan bayii ṣe si i.

Tẹ o ba gbagbe, Ize Iyamu yii ati Godwin Obaseki naa ni wọn jọ wa niwaju laarin awọn to fẹẹ jẹ gomina l’Edo lọdun 2016. Nigba yẹn, inu ẹgbẹ oṣelu APC ni Obaseki wa, bẹẹ lo ni atilẹyin nla lọdọ ẹni ti ṣe gomina ipinlẹ naa nigba yẹn, iyẹn Adams Oshiomhole. Ọmọ ẹgbẹ kan naa ni Obaseki ati Ize Iyamu, ṣugbọn nigba ti eto idibo n sunmọ, lo ti woye wi pe Obaseki lo ṣee ṣe ki ẹgbẹ ọhun lo, wọn ni eyi gan an lo mu Ize Iyamu lọọ darapọ ̀ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP. Ti wọn si jọ koju ara wọn.

Lọdun naa lọhun-un, ibo to le ni ẹgbẹrun lọna ọọdunrun (319, 483) ni Obaseki fi jandi Ize iyamu to dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP nigba yẹn mọlẹ. Ibo ti Iyamu ni si fi diẹ din ni ẹgbẹrun lọna ọtalelugba (253,173). Bọrọ ṣe ri lọdun naa niyẹn, nigba ti wọn jọ koju ara wọn.

Ninu ẹgbẹ oṣelu APC ni Obaseki wa titi, ṣugbọn nigba tawọn Oshiomhole gbe wahala wọn de, ti wọn kọ lati fun un ni tikẹẹti pada, eyi naa lo mu oun naa fi ẹgbẹ naa silẹ, to si gba inu PDP lọ.

Lana-an Satide, ọjọ Abamẹta, kaakiri ijọba ibilẹ mejidinlogun to wa nipinlẹ Edo ni ibo gomina ti waye, ti Godwin Obaseki si wọle ṣọọ pada sile ijọba.

 

Leave a Reply