Ibọn ati ọta rẹpẹtẹ ni wọn ba lapo Adigun atọrẹ ẹ ni Badagry

Faith Adebọla, Eko

Awọn afurasi ọdaran meji kan, Adigun Jeremiah, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ati Okorocha Covenant, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, ti wa lakata awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba, bayii. Ibẹ ni wọn ti n ṣalaye ohun ti wọn fẹẹ fi ibọn ti wọn ka mọ wọn lọwọ ṣe.

Irọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide yii, ni Alukoro ọlọpaa Eko, Olumuyiwa Adejọbi, sọ f’ALAROYE pe ọwọ tẹ awọn mejeeji. Wọn ni mẹta ni wọn, ọkada Bajaj kan ni wọn n gun lọ tawọn ọlọpaa teṣan Ilasan fi da wọn duro lori titi marosẹ to lọ lati Lẹkki si Ẹpẹ ni nnkan bii aago mẹsan-an aabọ alẹ.

Yatọ si pe awọn ti ọkada naa ko ju iye ero to yẹ ko gbe lọ, wọn ni ere asapajude ti wọn ba kọja lori titi naa mu ifura lọwọ, lawọn ọlọpaa ba gba tẹle wọn, ko si pẹ ti wọn fi le wọn ba.

Amọ bi wọn ṣe fẹẹ duro, niṣe ni ẹni kẹta ti wọn loun lo n wa ọkada naa ja awọn meji to gbe sẹyin silẹ, lo ba fi ọkada ẹ si jia, o sa lọ bẹẹ ni.

Nigba ti wọn maa yẹ ara awọn mejeeji ti ọkada ja ju silẹ wo, ibọn oyinbo alawọ goolu kan ni wọn ba lapo wọn, wọn ti loodu ọta sinu ẹ temu, wọn si tun ko awọn ọta rẹpẹtẹ sinu apo ṣokoto wọn.

Wọn lawọn ọlọpaa naa beere pe nibo ni wọn ti ri ibọn, ki si ni wọn fẹẹ fi i ṣe, iṣẹ wo ni wọn n ṣe, lọrọ ba di wo-mi-n-wo-ẹ, awọn afurasi ọdaran naa ko ri alaye gidi ṣe, wọn o si jẹwọ iṣẹ buruku ti wọn n tori ẹ mu ibọn kiri.

Bi wọn ṣe fọrọ naa to Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, Hakeem Odumosu, leti lo ni ki wọn tete maa ko awọn mejeeji lọ si Panti, wọn ni ọrọ wọn maa wulo lati tete ri ẹkẹta wọn mu, ki iwadii ti wọn maa ṣe lori ọrọ wọn le tete pari, tori ati gbe igbesẹ to kan.

Leave a Reply