Ibọn mẹta ni wọn ba lọwọ Mojeed atọrẹ ẹ ti wọn fi n jale ni Mushin

Faith Adebọla, Eko

 Adugbo kan wa ni Mushin ti wọn n pe ni Alakara, nipinlẹ Eko, ibẹ lọwọ awọn agbofinro ti tẹ gende mejikan, yii, Mojeed Satan, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, ati Kudaisi Ajetunmọbi, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, ti wọn fẹsun kan pe adigunjale gidi ni wọn.

Aago marun-in irọlẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni wọn lawọn afurasi mejeeji ko sakolo ọlọpaa nigba ti DPO ọlọpaa teṣan Alakara atawọn eeyan ẹ n patiroolu kiri agbegbe ọhun.

Alaye ti Olumuyiwa Adejọbi ṣe lori iṣẹlẹ ọhun ni pe ori ọkada Bajaj kan lawọn afurasi ọdaran mejeeji yii wa, awọn ọlọpaa lo fura si wọn, ni wọn ba da wọn duro, wọn yẹ ara wọn wo, lo ba di pe ibọn ilewọ pompo ti wọn n pe ni Beretta pistols, ni wọn ba lapo wọn.

Wọn tun ba mẹta ẹya ara ibọn ti wọn maa n ko ọta ibọn si tawọn eleebo n pe ni magasiini (magazine), lọwọ wọn pẹlu katiriiji ọta ibọn mejilelogun ti wọn o ti i yin.

Nigba tawọn ọlọpaa beere ohun ti wọn n fi ibọn ati ọta naa ṣe, wọn ko ri alaye gidi kan ṣe, ọrọ awọn mejeeji ko si jọ ara wọn. Wọn tun bi wọn leere iṣẹ ti wọn n ṣe, kantankantan ni wọn ni wọn n sọ jade, wọn o niṣẹ pato kan, lawọn ọlọpaa ba gba ẹru ofin ti wọn ko dani, wọn si fi pampẹ ọba gbe wọn.

Adejọbi lawọn afurasi mejeeji ti balẹ si Panti, ni Yaba, lọdọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ, ibẹ ni wọn ti n ṣalaye ara wọn fawọn to n ṣiṣẹ iwadii. Ti eleyii ba pari ni wọn yoo wọ wọn lọ siwaju adajọ lọrọ kan fun wọn.

Leave a Reply