Ibrahim Chatta ra mọto olowo nla lọdun tuntun

Adefunkẹ Adebiyi

Titi dasiko yii lawọn eeyan ṣi n ki gbajumọ oṣerekunrin nni, Ibrahim Chatta, ku oriire mọto olowo nla funfun kan to ṣẹṣẹ ra, eyi to gbe soju opo Instagraamu rẹ to si n fọpẹ f’Oluwa.

Niṣe ni ọkọ ayọkẹlẹ naa funfun gboo, to si rẹwa loju, awọn eeyan sọ pe ọpọlọpọ miliọnu lo le ra iru ẹ, bẹẹ ni Ibrahim naa fi i ya fọto oriṣiirisii pẹlu akọle to kọ sibẹ pe, “Oore-ọfẹ ni ojumọ kọọkan. Ọpẹ ni f’Ọlọun fun oore iwalaaye.”

Bo ti kọ ohun to kọ naa lawọn to ye ti mọ pe mọto to ṣẹṣẹ ja lo n sọrọ ba, bẹẹ ni kiki oriṣiiriṣii bẹre si i wọlẹ soju opo naa lọtun-un losi.

Awọn kan n sọ pe o tiẹ daa to jẹ ọkunrin lo ra mọto lọdun tuntun bayii ninu awọn onitiata, nitori awọn obiinrin ti wọn ko ṣiṣẹ gidi kan leeyan yoo ṣaa maa gbọ pe wọn ra mọto olowo nla.

Bẹẹ lawọn mi-in sọ pe ohun to tọ si Chatta ree. Wọn ni agba oṣere to n fi gbogbo ọpọlọ ṣiṣẹ ni, awọn si ba a yọ pe iṣẹ naa n seso rere fun un.

Leave a Reply