Ibrahim to gba ẹru ole sile ti dero kootu l’Aramọkọ Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Nitori pe o gba jẹnẹretọ ti wọn ji sile, ọkunrin ẹni ọgọta ọdun kan, Ọgbẹni Salisu Ibrahim, ti wa niwaju adajọ nile-ẹjọ Majisitreeti kan niluu Ado-Ekiti.

Ibrahim lawọn ọlọpaa gbe wa sile ẹjọ pẹlu ẹsun ẹyọ kan. Agbefọba, Insipẹkitọ Elijah Adejare, ṣalaye fun kootu pe iṣẹ aṣọna ni ọkunrin naa n ṣe nileewe girama kan to jẹ tijọba niluu Aramọkọ-Ekiti. Ṣugbọn ni deeede aago mọkanla alẹ ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹjọ, ọdun yii, afurasi ọdaran naa gba ẹrọ jẹnẹretọ kan ti iye rẹ to ẹgbẹrun lọna ọgọfa naira (N120,000), to jẹ ti Ọgbẹni Ilesanmi Babalọla lọwọ Richard Ejiro.

Ẹsun yii ni ile-ẹjọ sọ pe o lodi sofin irinwo ati mejidinlọgbọn (427) ofin iwa ọdaran ti ọdun 2012 tipinlẹ Ekiti n lo.

Agbefọba rọ adajọ lati funu n laaye ko le ṣagbeyẹwo awọn iwe ẹsun naa daadaa, ko si le ko awọn ẹlẹrii jọ lati waa jẹrii nile-ẹjọ

Ṣugbọn ninu awijare rẹ, agbẹjọro fun ọdaran naa, Ọgbẹni Timi Ọmọtọshọ sọ fun ile-ẹjọ pe onibaara oun ko jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an, o waa bẹbẹ fun beeli rẹ pẹlu ileri pe ko ni i sa lọ bi ile-ẹjọ ba tun pe e pada lasiko ti wọn ba fi igbẹjọ naa si.

Adajo Kay William fun ọdaran naa ni beeli pẹlu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira ati oniduuro meji to gbọdọ maa gbe ni agbegbe ile-ẹjọ. Lẹyin eyi lo sun igbẹjọ naa si ọjọ kẹfa, oṣu kẹsan-an, ọdun 2021.

Leave a Reply