ICPC fi panpẹ ofin gbe manija banki tawọn ọmọọṣẹ rẹ n fọna jibiti kowo sinu ẹrọ ATM

 Monisọla Saka

Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ atawọn ẹsun mi-in to jẹ mọ ọn lorileede Naijiria (ICPC), ti fofin gbe manija ile ifowopamọ kan niluu Oṣogbo, nipinlẹ Ọṣun, latari iwa ika to n fi ipo ẹ hu sawọn araalu, ati bi ko ṣe tẹle ofin banki apapọ ilẹ wa. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o pọn awọn owo Naira tuntun sinu lailọọnu fẹlẹfẹlẹ, lẹyin to we e pẹlu okun gẹgẹ bi bọndu owo ṣe maa n wa tan lo ko sinu ẹrọ to maa n pọ owo jade, ATM, eyi si jẹ ko ṣoro fun ẹrọ ATM ọhun lati pọ owo yii jade fawọn eeyan nitori bi o ṣe ti fi okun de e.

Gẹgẹ bii alaye ti wọn ṣe ni ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹta, oṣu Keji, ọdun yii, ti wọn kede ọrọ yii lori ẹrọ abẹyẹfo (Twitter), wọn. Gẹgẹ bi alaye ti wọn ṣe, wọn ni lodidi lodidi ti owo Naira tuntun ọhun wa ni ọga banki ọhun tun di i sinu ẹrọ ATM, bo ṣe di i yii ko jẹ ki owo naa jade sita.

Ninu ọrọ wọn ni wọn ti sọ pe, “Awọn ikọ ileeṣẹ ICPC ilu Oṣogbo, nipinlẹ Ọṣun, ya wọ ile ifowopamọ FCMB kan niluu ọhun, nibi ti wọn ti n kowo sinu ẹrọ ATM lai ja gbogbo lailọọnu ti wọn fi di owo naa kuro, eyi to si n ṣokunfa bi owo ko ṣe ribi jade. Awọn oṣiṣẹ ICPC yii waa paṣẹ pe ki wọn ja okun tẹẹrẹ ti wọn fi di owo ọhun ni bọndu bọndu ati lailọọnu ti wọn we mọ ọn lara, ki wọn si to o bo ṣe yẹ ko wa sinu ẹrọ apọwojade ọhun”.

Si iyalẹnu awọn ajọ yii, nigba twọn tun pada lọ sibẹ lọjọ keji lati lọọ wo o boya ayipada ti wa, wọn ri i pe wọn ṣi ko awọn owo bọndu ti wọn ko ti i ja beba ati lailọọnu ara ẹ sinu ẹrọ ATM kan nibẹ. Iwọnba eyi to n ṣiṣẹ lawọn ogunlọgọ ero ti wọn to lọ rẹrẹ lati gbowo si n ba ja. Lojuẹsẹ ni wọn gbe manija banki ọhun lọ si olu ileeṣẹ wọn nipinlẹ ọhun fun ifọrọwanilẹnuwo.

Tẹ o ba gbagbe, latigba ti olori banki apapọ ilẹ wa, Godwin Emefiele, ti paṣẹ fawọn ile ifowopamọ gbogbo lorilẹ-ede yii, lati maa san owo Naira tuntun fawọn araalu, lo ti kede pe awọn yoo fọwọsowọpọ pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa atawọn ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ lorilẹ-ede yii, EFCC, ICPC atawọn ileeṣẹ mi-in tọrọ kan, lati le ri i daju pe ofin tawọn ṣe mulẹ, awọn si fopin si ṣiṣe owo Naira mọkumọku.

Leave a Reply