ICPC mu oṣere tiata to n ta owo Naira tuntun

Monisọla Saka

Ajọ to n ri si iwa ibajẹ atawọn ẹsun to ba jọ mọ ọn, Independent  Corrupt Practices and Other Related Offences (ICPC), ti mu ọkan ninu awọn oṣere ilẹ wa, Ọmọsẹyin Oluwadara Esther, ṣugbọn ti gbogbo eeyan mọ si Sinmisọla Gold, pe o n ta owo Naira ilẹ wa. Ori ayelujara ni oṣere naa gba lọ, to ti kede fun gbogbo aye pe oun n ta owo tuntun ti wọn ṣẹṣẹ ṣe jade ti ọpọlọpọ eeyan n daamu lati ri naa.

Oṣere ti wọn lo tun maa n ta ipara, epo bẹntiroolu, bẹẹ lo tun maa n ba awọn ti wọn ba fẹẹ rin irina-ajo lọ silẹ okeere ṣeto ẹ, to si tun n ṣe awọn iṣẹ oriṣiiriṣii mi-in ni Alukoro ICPC, Azuka Ogugua, ni o lo anfaani owo Naira ilẹ wa ti ko fi bẹẹ si nita lati maa ta owo naa ni gbangba, to si n kede rẹ lori ayelujara.

Ogugua sọ pe awọn kan ni wọn waa ta awọn lolobo lọjọ kin-in-ni, oṣu Keji yii, nipa ohun ti ọmọbinrin naa n ṣe. Eyi lo jẹ ki ajọ naa jade, ti wọn si ṣọ oṣere naa titi ti wọn fi ri i mu.

O fi kun un pe oṣere yii lo lẹdi apo pọ pẹlu awọn kan ti wọn jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ eto inawo, ti wọn wọn si n ko owo naa kuro ninu banki ati awọn ibi gbogbo ti wọn ti n san an, ti wọn si n lọọ ta a ni ita fun awọn eeyan lọna ẹburu.

Alukro naa sọ pe wọn ti fi ọwọ ofin gbe oṣere yii, o si ti wa lokolo ICPC, nibi to ti n ran wọn lọwọ lori iwadii wọn lori owo Naira tita ati ipalara to le mu ba ọrọ aje ilẹ wa.

Ṣugbọn ọtọ loju ti ọpọ eeyan fi wo ọrọ naa, ọrọ buruku lawọn kan n sọ si ajọ naa pẹlu bi wọn ṣe mu ọmọbinrin yii, wọn ni eyi ti wọn ni ki okobo wọn bọ, wọn ko bọ ọ. Ọkunrin kan kọ ọ sabẹ iroyin naa lori Instagraamu ICPC pe, ‘awọn ICPC yii ko le mu ileeṣẹ banki apapọ ilẹ wa atawọn oṣiṣẹ wọn to n ko owo naa jade fun awọn eeyan. Ẹ wa si Jobi Fẹlẹ Way, n’Ikẹja, ki ẹ waa wo bi wọn ṣe n ta owo fun awọn oloṣelu lọkunrin ati lobinrin.

Ẹnikan to pera ẹ ni homestyle_dishes sọ pe ‘ Ṣe ni ki ẹyin eeyan wọnyi lọọ mu awọn manija banki ti wọn n ta owo tuntun yii nitori imọtara wọn nikan. Kẹ ẹ tun mu awọn to n ta owo naa lawọn kilọọbu ati ni pati kaakiri, ti awọn mẹkunnu si wa nibẹ ti iya n jẹ wọn. Ebi n pa awọn eeyan ku, awọn meji ni wọn ku sileewosan lanaa, alaboyun kan ti ọmọ ọdun marun-un kan, nitori ko si owo ti wọn le san silẹ lọsibitu ati eyi ti wọn le fi ra oogun. Oju opo ko si ja gaara lanaa to fi jẹ pe wọn ko le fi owo ranṣẹ si asunwọn ẹlomi-in. Ninu gbogbo ohun ti a ba n ṣe, ẹ jẹ ka maa ranti pe Ọlọrun to da wa wa laaye, yoo si ṣedajọ onikaluku lasiko to ba yẹ.’

Leave a Reply