Jide Alabi
Titi di asiko yii ni ileeṣẹ ọlọpaa ṣi n sọ pe Aarẹ Muhammad Buhari lo n da awọn lọwọ kọ nipa ọga tuntun ti yoo gbaṣẹ lọwọ ọga patapata ninu iṣẹ ọlọpaa, Muhammed Adamu.
ALAROYE gbọ pe Adamu to yẹ ko ti fẹyinti lẹnu iṣẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ti mura lati maa lọ, ṣugbọn oju Buhari lọkunrin naa ṣi n wo pe boya o ṣee ṣe ko ni ki oun ṣi wa nipo naa.
Wọn ni bi Buhari ko ṣe ti i sọ ohunkohun yii ko jẹ ki ọga ọlọpaa naa mọ eyi ti ko ba ṣe gan-an, nitori ko le lọ lai jẹ pe Buhari ba pa a laṣẹ, bakan naa ni ko le farabalẹ sipo ọhun lai ma ṣeto bi yoo ṣe fa iṣẹ le ẹlomi-in lọwọ.
Ipo ti wọn sọ pe Muhammed Adamu wa niyẹn o. Bẹẹ lawọn kan ti bẹrẹ si i dunnu bayii pe ọkunrin ọlọpaa kan ti ipo ẹ tun ga ju, Igbakeji ọga patapata, Zanna Ibrahim, lo ṣee ṣe ki Buhari yan gẹgẹ bii ẹni ti yoo di adele ọga agba ni Naijiria.
Ni kete ti iroyin ọhun ti gba igboro kan lawọn eeyan tiẹ nileewe awọn ọlọpaa to wa ni Wudil, nipinlẹ Kano, naa ti n jo, ti wọn n yọ, lọjọ Iṣẹgun,Tusidee, ọsẹ yii, pe oye naa ti kan agbegbe awọn niyẹn.
Ohun ti awọn kan si n sọ ninu wọn ni pe, oun ni ipo ẹ tun ga lẹyin ti wọn ba ti mu Muhammed Adamu tan, ati pe bi awọn ṣe n gbọ ọ kiri, wọn lo ṣee ṣe ki Buhari yan an sipo ọhun.
Bo tilẹ jẹ pe ọjọ Aje, Mọnde, niṣẹ ẹ pari ninu iṣẹ ọlọpaa, sibẹ, ọga ọlọpaa yii naa lo tun lọọ pade Muhammadu Buhari lọjọ Iṣẹgun, nigba ti Aarẹ pada siluu Abuja, lẹyin isinmi ranpẹ to gba lati lọọ forukọ silẹ niluu ẹ ni Daura lọsẹ to kọja. Wọn leyii fi han pe ọkunrin naa ṣi n ba iṣẹ ẹ lọ.
Ṣa o, Buhari ko ti i wi ohunkohun, awọn agbẹnusọ ẹ paapaa lawọn ko ti i mọ ohun ti ọga awọn fẹẹ ṣẹ, bẹẹ ni ọkan Muhammed Adamu paapaa ko balẹ, nitori ko mọ eyi ti iba ṣe gan an.
Bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan kan sọ pe ni kete ti Buhari ti pada sẹnu iṣẹ ni igbesẹ ti waye pe ki ọga ọlọpaa naa fa gbogbo ohun to ba wa nikaawọ ẹ le ọlọpaa ti ipo ẹ ga ju lọ lọwọ, sibẹ, ikede kankan ko ti i waye lati ọfiisi Aarẹ, bẹẹ gẹgẹ lawọn eeyan ko ti i le sọ boya ọkunrin yii yoo tẹsiwaju lẹnu iṣe tabi yoo maa lọ niwọn igba ti ọdun marundinlogoji to yẹ ko lo lẹnu iṣe ti pe ni ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.