Idaamu Baba Ijẹṣa: Adajọ da ẹjọ kotẹmilọrun to pe nu, wọn ni dandan ni ko lo ọdun marun-un lẹwọn

Adewale Adeoye

Ẹsẹ ko gbero nile-ẹjọ kotẹmilọrun kan to wa niluu Ikeja, nipinlẹ Eko, lasiko igbẹjọ ti adẹrin-in-poṣonu nni, Ọgbẹni Ọlanrewaju James, ẹni tawọn eeyan mọ si Baba Ijesha pe,  lati din iye ọdun ti Onidaajọ Oluwatoyin Taiwo ju u si lọjọ kẹrinla, oṣu Kẹjọ, ọdun 2022 ku.

Awọn alaṣẹ ijọba ipinlẹ Eko ni wọn ba Baba Ijesha ṣẹjọ lori ẹsun iwa ti ko bofin mu wọn fi kan an pe o n ba ọmọde kan tọjọ ori rẹ ko ju ọdun mẹrinla lọ ṣere egele. Iwaju Onidaajọ Oluwatoyin Taiwo, tile-ẹjọ akanṣe kan to n ri si lilo ọmọde nilokulo ati fifipa ba awọn obinrin sun, ‘Special Offences Court’, to wa niluu Ikeja, nipinlẹ Eko, ni wọn wọ Baba Ijesha lọ nigba naa lọhun-un. Ẹsun mẹfa ọtọọtọ, ninu eyi ti igbiyanju lati ba ọmọde ni nnkan pọ, lilo ọmọde nilokulo ati bẹẹ bẹẹ lọ wa ni wọn fi kan oṣere yii.  Lẹyin gbogbo atotonu oun ati ti lọọya rẹ, adajọ ju u sẹwọn ọdun marun-un pẹlu iṣẹ aṣekara lọgba ẹwọn Kirikiri, niluu Eko.

Nigba ti igbẹjọ rẹ  waye l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun yii, Onidaajọ Fọlashade Ojo to ṣaaju ikọ adajọ ẹlẹni mẹta kan to n gbọ ẹjọ rẹ ni ko si awijare kankan fun olujẹjọ nipa ẹjọ kotẹmilọrun to pe. Pe o gbọdọ lo iye ọdun ti Onidaajọ Abilekọ Taiwo da fun un lọgba ẹwọn.

O ni ọrọ to sọ lọdọ awọn ọlọpaa Sabo, lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2021, ati lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2021, nipa ipa to ko ninu ẹsun ti wọn fi kan an ko yatọ rara.

Pẹlu idajọ yii, ireti Baba Ijẹṣa lati tete kuro lọgba ẹwọn ti ja si pabo, afi bo ba tun gbe ẹjọ naa lọ si ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa lo ku.

Leave a Reply