IDAAMU OLUWOO: Ọba to ti ṣẹwọn l’Amẹrika nigba kan

Loootọ ni Ọba naa ti n jagun tipẹ, bo tilẹ jẹ pe ọpọ ogun naa jẹ afọwọfa, to jẹ bo ti n jagun lo n ṣẹgun awọn ọta ati alatako, ogun to koju Oluwoo Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi, bayii, afaimọ ko ma ba ogun naa lọ. Idi ni pe ogun eyi le, bẹẹ ni ki i ṣe awọn araata lo gbe ogun naa waa ba a, awọn araale ni. Awọn ọmọ ilu Iwo ti wọn wa nilẹ-okeere, kaakiri awọn ilu nla, ni wọn gbarajọ ti wọn kọwe sijọba ipinlẹ Ọṣun, ti wọn ni ki ijọba naa yọ Ọba Akanbi kuro lori oye, nitori awọn iwa afiniṣẹsin ati awọn iwa buruku mi-in to kun ọwọ rẹ gbogbo. Wọn ni ọkunrin yii ti ba gbogbo iyi to wa lara ilu Iwo jẹ, o si ti sọ ilu naa di yẹpẹrẹ kari ilẹ Yoruba, ati loju awọn ẹya mi-in gbogbo. Ohun to tilẹ mu ọrọ naa le diẹ ni pe ki i ṣe pe awọn ẹgbẹ naa da kọwe naa, lọọya ni wọn gba to kọ ọ sijọba, iyẹn ni pe ọrọ naa ṣoro o pa mọlẹ.

Lọkọọkan ni wọn ka ẹsun si Ọba Akanbi lẹsẹ, apapọ ẹsun ti wọn si ka si i lẹsẹ jẹ mẹtalọgbọn. Ibi ti wọn ti bẹrẹ ni pe Ọba Akanbi sa jade nipebi ni, wọn ni ko duro ṣe gbogbo etutu to yẹ ko ṣe, eyi ti ko fi yẹ ko gba ọpa aṣẹ rara. Ọtọ ni wọn sọ ti pe bo ṣe gboye lo ti bẹre si i fa kuraku kaakiri, ẹni akọkọ ti yoo si kọ lu ni Oluwoo Oke, Iwo Oke, aafin Ọọni ni Ileefẹ lo ti kọkọ kọ lu ọba naa, to si pada dẹ awọn tọọgi si i, ti wọn si ba awọn ohun-ini rẹ to wa ni Iwo jẹ. Ọrọ naa di ti ile-ẹjọ, ti Adajọ pe Oluwoo, ṣugbọn ti ko yọju, ko too di pe iyẹn ni kawọn ọlọpaa mu un nibikibi ti wọn ba ti ri i. Lẹyin naa ni wọn fẹsun kan an pe o pe ara rẹ ni Ẹẹmaya, orukọ awọn Ọba ilẹ Hausa, ati pe gbogbo ọba nla nla nilẹ Yoruba ni Ọba Akanbi ti fẹrẹ ri fin tan pata. Ọba Akanbi yii naa lo si le lemọọmu Iwo kuro ni yidi, to ni oun loun gbọdọ ṣaaju irun.

Lẹyin naa lawọn eeyan fẹsun kan Kabiyesi yii pe o gbe ade le ori iyawo rẹ laafin, o si pe e ni ọba obinrin. Wọn ni oriṣiiriṣii awọn obinrin lọba yii n ba sun, ati iyawo oniyawo ati awọn ọmọ kekere gbogbo, gẹgẹ bii ẹsun tiyawo rẹ fi kan an, ọrọ naa si le debi ti olori ile-ẹkọ Bowen University, n’Iwoo fi ni ki Oluwoo yee waa sare kiri ninu ọgba ileewe awọn mọ, ti yoo ni oun n ṣe ẹsasaisi. Nitori bo ba ti wa bẹẹ to ni oun n ṣere idaraya yii, awọn ọmọbinrin ileewe naa lo waa n fọgbọn mu. Wọn ni oriṣiiriṣii ẹjọ ni Ọba Akanbi ni ni kootu, paapaa laarin oun ati Oloye Abiọla Ogundokun, ile-ẹjọ si ti da a lẹbi daadaa ri. Wọn ni tọọgi lo maa n ko kiri ti yoo fi maa dẹru ba awọn eeyan ilu, ti ko ni i si ẹni kan to le koju ẹ, igba kan si wa ti oun gẹgẹ bii odidi ọba ilu gbe mọto ti ko lori jade, to si duro ninu mọto naa, to n bu Ogundokun kiri laarin Iwo.

Ṣugbọn ọpọlọpọ awọn ẹsun ti wọn fi kan Oluwoo yii, lara awọn ogun to ti ja to ti ṣẹ ni, bo ba si jẹ awọn ogun yii ni, bi wọn ju abẹbẹ soke nigba igba, ibi pẹlẹbẹ naa ni yoo maa fi lelẹ, ọba naa yoo maa jagun-ṣẹgun ni. Ṣugbọn ẹsun kan wa to le ju ninu awọn eyi ti wọn hu jade yii, iyẹn naa ni nibi ti wọn ti fi ẹsun kan Ọba Adewale pe o ti ṣewọn niluu oyinbo ri, iyẹn ni Amẹrika, wọn si le e jade ni orilẹ-ede naa ni nitori iwa ọdaran rẹ. Wọn ni ko si tabi ṣugbọn nibẹ, bi ijọba ipinlẹ Ọṣun ba ṣewadii ọrọ yii ni Ẹmbasi Amẹrika ni Naijiria nibi, kia ni wọn yoo ri alaye ohun ti awọn n sọ. Ẹsun yii tobi pupọ, ohun to si mu ko tobi ni pe ẹni yoowu ti wọn ba ti ran lẹwọn ri, to ti ṣẹwọn nibikibi, ko lẹtọọ lati ṣiṣẹ ilu mọ labẹ ofin, bẹẹ iṣẹ ilu ni iṣẹ ọba, afi to ba jẹ ijọba ti dari ji tọhun, ti wọn si pa orukọ rẹ̀ rẹ́ kuro ninu iwe awọn ẹlẹwọn.

Ṣugbọn ni ti Ọba Raṣidi yii, ko si ijọba kan to pa orukọ rẹ rẹ, tabi ti wọn dari ji i, nitori ko sọ fẹnikẹni pe oun ṣẹwọn nibi kan ri, ko si sọ pe oun ti daran ijọba Amẹrika ki oun too waa jọba. Eleyii funra rẹ, ẹsun buruku ni laaye ọtọ, enikẹni ti yoo ba gba iṣẹ ilu, ẹtọ ni lati sọ gbogbo ibi to ti rin si, ati lati sọ boya o ti ṣẹ sofin ijọba ibi kan ri, ti yoo si ṣalaye idi ẹṣẹ naa ati iru iya ti wọn fi jẹ oun, tabi ibi ti ọrọ ọhun yọri si. Awọn ọmọ ilu Iwo ti wọn fẹsun kan Oluwoo ni ko ṣalaye ọrọ naa fun awọn afọbajẹ, ko si wi kinni kan funjọba lori ẹ, o bo gbogbo ọrọ naa mọlẹ pa ni. Eyi lawọn eeyan naa ṣe ni ki ijọba sare wadii ọrọ naa, wọn yoo si ri ohun tawọn n sọ, bo ba si jẹ loootọ ni, ki wọn sare da sẹria to ba yẹ fun Oluwoo, Raṣidi Adewale Akanbi, ọba to ti sẹwọn l’Amẹrika nigba kan.

A gbọ ẹjọ ẹni kan dajọ, agba oṣika ni. Ki ọrọ ma di pe wọn purọ mọ ọba yii ni, ALAROYE ṣewadii ọrọ naa finnifini, a si ri i pe loootọ ni wọn ju Ọba Akanbi sẹwọn ni Amẹrika nibẹrẹ ọdun 1998 fun iwa ọdaran bii ṣiṣe ati nina ayederu owo, pẹlu jiji kaadi igbowo ati ti ẹyawo gbe, ati lilu jibiti loriṣiiriṣii. Orukọ to n jẹ nigba to ṣẹwọn yii ni Ṣẹgun Adewale Adeonigbagbe, nọmba ẹwọn rẹ si ni BOP ID 10673 -068. Ọjo to jade lẹwọn naa ni ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹta, ọdun 1999. Gbara to jade lẹwọn naa ni wọn ṣu u rugudu, wọn da a pada si Naijiria pẹlu iwe ati ikilọ pe ko gbọdọ wọ orilẹ-ede Amẹrika mọ laye rẹ. Ṣugbọn lẹyin ti Oluwoo ti wọ Naijiria, o tun ṣe awọn eto kan, o si tun gbera paa, orilẹ-ede Canada lo balẹ si. Nibẹ lo wa to ti n fẹ awọn iyawo, to si n bi awọn ọmọ.

Ni o ku bii ọdun mẹrin ti Adewale yoo di Oluwoo, ọkunrin naa tun ko si ọwọ ofin wọn ni Amẹrika yii kan naa. Ohun  to ṣẹlẹ ni pe o fẹẹ ba ọna ẹburu pada wa si orilẹ-ede naa, o si gba ẹnubode kan ti wọn n pe ni Peace Bridge wọle. Ni wọn ba tun ra a mu, eleyii jẹ ọjọ kọkanla, oṣu kẹta, ọdun 2011. Lati ọjọ ti wọn ti mu un yii, wọn la a mẹwọn ni, wọn ko fi i silẹ, wọn n ba a ṣe ẹjọ lọ, nigba ti oun naa si ri i pe ọrọ ti daru pata, o jẹwọ pe oun lẹni naa, oun ni wọn n wa, nitori o ti yi orukọ pada tẹlẹ, o ti pe ara rẹ ni Ọmọọba Adewale Akanbi, nigba to tẹka ni aṣiri tu pe Adeonigbagbe ti wọn ti le niluu tẹlẹ naa ni. Ni ọjo kẹsan-an, oṣu kẹjọ, 2011, ẹka to n ṣeto idajọ (Department of Justice) lorilẹ-ede Amẹrika gbe iwe kan jade, ohun to wa nibẹ niyi:

Nigerian man pleads guilty to attempting to enter the United States After being deported (Ọmọ Naijiria kan loun jẹbi ẹsun lati wọ ilẹ Amẹrika lẹyin ti wọn ti kọkọ le e jade). Olupẹjọ Agba fun ijọba US, William J. Hochul, kede loni-in pe Ṣẹgun Adewale Adeonigbagbe, ọmọ Naijiria kan ti jẹwọ niwaju Adajọ William M. Skretny, pe loootọ loun jẹbi ẹsun pe oun tun fẹẹ gbẹburu wọ ilẹ US, leyin ti wọn le oun jade nigba ti oun huwa aburu kan to yẹ ki wọn tori ẹ ju oun sẹwọn ogun ọdun, tabi ki wọn ni ki oun san owo itanran to jẹ aadọtalerugba ẹgbẹrun owo dọla ($250,000), tabi ki wọn pa ijiya mejeeji pọ foun. Olupẹjọ ijọba to n ṣe ẹjọ yii, Michael Digiacomo, sọ pe ni ọjọ kọkanla, oṣu kẹta 2011, ọdaran yii wọ ilẹ Amẹrika lati ẹnu-ibode Peace Bridge. Kọmputa lo beere pe ki lọkunrin naa tun n wa nigba ti wọn ti le e jade tẹlẹ ni Amẹrika ni 1999, lẹyin to ti ṣẹwọn lati 1998 nitori iwa jibiti loriṣiiriṣii. Ọjọ kọkanlelogun, oṣu kọkanla, ni Adajọ Skretiny yoo dajọ rẹ.

Ẹjọ ti wọn da fun Adewale ko pọ nitori nigba naa, o ti ni iwe igbeluu ni Canada, bii ara Canada ni wọn si ṣe ri i, wọn ko ri i bii ara Naijiria. Wọn ro ọjọ to ti fi wa lẹwọn pọ mọ iye ẹwọn ti wọn da fun un, ewọn naa si pe lọjọ kọkandinlogun, oṣu kejila, ọdun 2011 yii, kan naa, ọjọ naa si ni Adewale jade kuro lẹwọn ẹlẹẹkeji yii lẹyin to ti wa nibẹ lati ọjọ kọkanla, oṣu kẹta. Awọn iwadii yii fi han pe loootọ ni Ọba Akanbi ti ṣẹwọn ni Amẹrika daadaa ri, ohun tawọn ti wọn fẹsun kan an si kọ sita ree. Iwe ti wọn kọ yii wa lọwọ Gomina Adegboyega Oyetọla, o wa lọwọ alaga ile-igbimọ aṣofin Ọṣun, olootu eto idajọ ipinlẹ Ọṣun, kọmiṣanna fun ọrọ oye, igbimọ lọbalọba ipinlẹ Ọṣun, ati alaga ijọba ibilẹ agbegbe Iwo. Ọrọ si ti debi waa-wi-tẹnu-ẹ fun Oluwoo, esi si ni gbogbo aye n reti o.

4 thoughts on “IDAAMU OLUWOO: Ọba to ti ṣẹwọn l’Amẹrika nigba kan

  1. Ìgbé èdè kalẹ̀ yín wúni lórí jọjọ, kò rújú bẹ̀ẹ́ ni gbogbo oní làákàyè ènìyàn mọ̀ pé ìwà ọmọ gànfe , ọmọ ìsọta kún ọwọ́ Ọba Àkànbí. Èéfín nì wà lọ̀rọ̀ aláparútu yìí, gbogbo ọ̀rọ̀ kọ̀kọ̀ ní gbangba ló n bọ̀

  2. Beni, oro sununkun, oju sununkun ni a nfi wo, (proverb) omi tutu lo nti enu eja bo, oro tutu ni yo tenu temi jade. Abamo o ni keyin oro mi, eyin nko?

  3. Esun ti ko lese nle ni eso fun won ki won waesun mi gbogbo eee patapata ibere otee niolorun lonfi oba je olorun so niyo oba nipo ekuro nidi ote gbogbo eyan mope oloye ogundokun lowa labe oro yi

Leave a Reply