Idanwo aṣekagba NECO yoo bẹrẹ pada lọjọ Aje to n bọ

Faith Adebọla, Eko

Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to n bọ yii, ni idanwo aṣekagba awọn oniwee mẹwaa SSCE, yoo bẹrẹ pada jake-jado Naijiria.

Ajọ to n ṣeto idanwo ọhun, National Examinations Council, NECO, lo kede bẹẹ lọsan-an ọjo Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ninu atẹjade kan ti Alukoro ajọ naa, Ọgbẹni Azeez Sanni, fi sode.

O ni, “Eyi ni lati sọ fun gbogbo awọn akẹkọọ, olukọ, ileewe atawọn mi-in tọrọ kan pe idanwo oniwee mẹwaa Senior School Certificate Examinations (SSCE) ti ọdun 2020 yoo bẹrẹ pada kaakiri Naijiria lọjọ Aje, ọjọ kẹsan-an, oṣu kọkanla yii.

“Ilana tuntun nipa awọn iṣẹ kọọkan ati ọjọ ti wọn maa ṣe e maa jade sori ikanni ajọ NECO l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrin, oṣu yii, a si rọ gbogbo yin lati lọọ wa a jade nibẹ kẹ ẹ le mọ asiko tawọn idanwo naa maa waye.”

Tẹ o ba gbagbe, rukerudo to waye latari iwọde ta ko ọlọpaa SARS ati ofin konilegbele to tẹle e lo mu ki wọn so eto idanwo to n lọ lọwọ lasiko ọhun rọ̀ lọjọ kẹẹẹdọgbọn, ọṣu kẹwaa, iyẹn osẹ to kọja yii.

Ajọ naa dupẹ fun suuru ati aibinu awọn obi ati akẹkọọ, wọn si tọrọ aforiji fun wahala ti siso ti wọn so eto idanwo naa rọ̀ ba mu ba wọn.

Leave a Reply