Ideye darapọ mọ Goztepe ilẹ Turkey

Oluyinka Soyemi

Agbabọọlu ilẹ Naijiria, Brown Ideye, ti darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Goztepe ilẹ Turkey.

Gẹgẹ bi awọn alaṣẹ kilọọbu naa ṣe sọ, iwe adehun ọlọdun meji ni agbabọọlu ẹni ọdun mọkanlelọgbọn ọhun tọwọ bọ.

Turkey ni orilẹ-ede kẹsan-an ti Ideye yoo ti gba bọọlu, ilẹ Naijiria lo si ti bẹrẹ ko too lọ Switzerland, France, Ukraine, England, Greece, Spain ati China.

Lati ọdun 2007 lo ti n gba bọọlu fun Naijiria, Flying Eagles lo ti bẹrẹ ko too wọ Super Eagles.

Leave a Reply