Idi ti ebi yoo fi pa Yoruba ti awọn Hausa ba dẹyẹ si wa- Ọjọgbọn Adejumọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Pẹlu bi ọpọ ọmọ Yoruba ṣe pa iṣẹ agbẹ ti, to si jẹ pe ounjẹ ti wọn n ko wọ ilẹ yii lati ẹyin odi lo pọ ju ninu ounjẹ ti a n ra jẹ lojoojumọ, nnkan ko ni i rọgbọ fun ẹya Yoruba bi awọn ara iha Ariwa orileede yii ba dẹyẹ si wa.

Eyi jẹ yọ ninu idanilẹkọọ ti alakooso tẹlẹ feto ẹkọ ni ipinlẹ Ọyọ, Ọjọgbọn Sọji Adejumọ, ṣe nibi apero ti awọn aṣaaju ilẹ Yoruba ṣe lori eto aabo ni gbọngan Mapo, n’Ibadan, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yìí.

Nigba to n ṣapejuwe awọn ẹya Hausa ati Fulani gẹgẹ bii ẹya to n ṣowo aṣejere lorileede yii ju lọ, Ọjọgbọn Adejumọ woye pe owo yii lo ṣee ṣe ki wọn maa lo lati fi ra ibọn atawọn nnkan ija rẹpẹtẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Iwadii fi han pe ọja to to bii  miliọnu lọna ọgọrun-un naira (N100m) lawa Yoruba n ta si ilẹ Hausa lọdọọdun. Eyi ti awọn n ta sọdọ tiwa jẹ ọja ẹẹdẹgbẹta biliọnu naira (N500b) lọdọọdun.

A waa ni wọn n rowo ra ibọn AK47. Bilionu marun-un naira ti to lati ra ohun ija oloro ninu owo ti wọn n pa latọdọ wa yii.

“Ta a ba da ilẹ wọn nilẹ Hausa si ọgọrun-un (100), ida marundinlogoji (35) pere ninu ẹ lo ṣee dako. Ṣugbọn wọn ni ọpọlọpọ ẹrọ nla nla ti wọn fi n bu omi rin oko wọn. Koda, eyi to kere ju ninu ẹrọ ti wọn fi n bu omi rin oko lo le wẹẹti oko to to ẹgbẹrun mẹfa (6,000) eeka.

“Ṣugbọn bi awọn Hausa ṣe n lo ajilẹ si ilẹ tiwọn fún ilọsiwaju iṣẹ ọgbin, pipa lawa n pa ilẹ tiwa ṣaa. Bẹẹ lawọn Fulani naa tun n ko awọn ẹran wọn waa jẹ iwọnba oko ta a ba da.

“Ilẹ Hausa n pese ọkababa, ata, tomaati, ireke ati iṣu, nitori wa (Yorùbá) ni wọn si ṣe n gbin awọn nnkan wonyi. Ta a ba da ire oko wọn si ọgọrun-un, awọn funra wọn ki i jẹ kọja ida marundinlogoji (35) ninu ẹ. Awọn ara Oke-Ọya lo n sin ẹran ju ṣugbọn awọn ni wọn n jẹran to kere ju, awa la n fowo ra eyi to pọ ju ninu ẹran wọn.

“Maaluu ẹgbẹrun mẹfa (6000) ni wọn n jẹ l’Ekoo lojumọ; ọgọsan-an (1800) maaluu la n pa ni ipinlẹ Ọyọ lojumọ; Ekiti n jẹ irinwo (400) maaluu; Ọṣun, ẹgbẹrin (800); Ogun; ẹgbẹrun kan (1000), nigba ti maaluu ti wọn n pa l’Ondo lojumọ jẹ ẹgbẹta (600).

“Bi wọn ṣe wa n rowo pa lori okoowo to yii, bẹẹ naa ni wọn n pawo lọwọ wa nipasẹ iṣẹ ajinigbe ti wọn tun n ṣe laarin wa”

Nigba to n sọrọ lori ọna abayọ, Ọjọgbọn Adejumọ sọ pe ọna abayọ ni ki awọn ijọba ilẹ Yoruba mu eto ọgbin ni pataki gẹgẹ bi awọn Oloogbe Ọbafẹmi Awolọwọ ṣe ṣe e lasiko ijọba ẹlẹkunjekun, ti ijọba ilẹ Yoruba fi lowo lọwọ to bẹẹ ti wọn fi n ya ijọba apapọ Naijiria lowo.

Bakan naa lo sọ pe o ṣe pataki ki awọn gomina ilẹ Yoruba ṣeto naa pẹlu ifọwọsowọpọ laarin ara wọn to fi jẹ pe ipinlẹ ti ko ba le ṣe ọgbin ounjẹ kan yoo le maa fi iru ounjẹ bẹẹ pese nnkan mi-in.

Nigba to n sọrọ lori ọrọ ibujẹ ẹran ti wọn n pe ni RUGA, eyi ti ijọba apapọ n gbero lati da silẹ fawọn Fulani to n sin maaluu kaakiri orileede yii, ọjọgbọn naa sọ pe “ko si ohun to buru ninu RUGA, ṣugbọn awa funra wa la ni lati ṣe e fun anfaani ara wa.

“Awọn aaye wọnyi wúlò fun ọsin maaluu ta a le máa jẹ nilẹ Yorùbá funra wa: Faṣọla ni ipinlẹ Ọyọ; Imẹkọ (Ogun), Ọdẹda ni Ogun, Iwo (Ọṣun), Agege ati Ikorodu ni ipinlẹ Eko ati bẹẹ bẹẹ lọ.”

Leave a Reply