Idi ti Jonathan ko fi le dupo aarẹ lọdun 2023- Falana

Monisọla Saka
Idi ti Jonathan ko fi le dupo aarẹ lọdun 2023- Falana
Agbẹjọro to tun jẹ ajafẹtọọ ọmọniyan nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Fẹmi Falana, ti sọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, pe aarẹ ilẹ wa tẹlẹ, Goodluck Ebele
Jonathan, ko le jade dupo aarẹ to n bọ lọna lọdun 2023, nitori ofin ilẹ wa ọdun 1999 ta ko o.
Awuyewuye ti n lọ labẹnu pe aarẹ tẹlẹri ọhun le fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ lọ si ẹgbẹ to n ṣejọba lọwọ, iyẹn APC.
Ọdun 2011 ni wọn dibo yan Jonathan gẹgẹ bii aarẹ, ṣugbọn ti ibo naa pada ja sọwọ Muhammadu Buhari lọdun 2015.
Agba lọọya ọhun sọ ninu atẹjade kan to fi dahun si bi awọn kan ṣe n sọ fun Jonathan lati jade waa dupo aarẹ ọdun 2023 pe Ọgbẹni Jonathan to ti jẹ aarẹ ilẹ yii latọdun 2010 titi di 2015, yoo
ba ofin to de iye saa ti eeyan gbọdọ lo lori ipo aarẹ ti i ṣe saa meji, to tun jẹ ọdun mẹjọ jẹ, to ba fi le jade dupo lọdun to n bọ, to si jawe olubori.
O mu un wa si irannileti pe Jonathan di aarẹ Naijiria lẹyin ti Aarẹ Umaru Yaradua ṣadeede ku, oun lo si pari saa ijọba ti Yaradua n ba lọ. Lẹyin naa lo ṣẹṣẹ tun waa gbegba ibo lọdun 2011, to si wọle.
Falana fi kun ọrọ rẹ pe ọdun marun-un ni Jonathan lo nipo aarẹ, to ba tun waa fi le wọle aarẹ lọdun to n bọ yii, yoo jẹ ọdun mẹsan-an to lo gegẹ bii aarẹ orilẹ-ede Naijiria, eyi ko si ba ofin mu.

“Ọmọwe Jonathan o lẹtọọ lati dupo aarẹ ọdun 2023. Idi ni pe to ba wọle ibo aarẹ, yoo tun fẹẹ lo ọdun mẹrin si i.
“Eyi tumọ si pe, yoo lo ọdun mẹsan-an lapapọ gẹgẹ bii aarẹ ilẹ Naijiria, leyii ti ko si ni ibamu pẹlu abala mẹtadinlogoje iwe ofin ilẹ wa, eyi to fi lelẹ pe saa meji to jẹ ọdun mẹjọ ni ọdun to pọ ju teeyan le lo lori aleefa.
O tẹsiwaju pe, “Ẹnikẹni ti wọn ba ti bura wọle fun ri lati pari saa ẹlomi-in ti wọn dibo yan gẹgẹ bii aarẹ, ko lẹtọọ lati wọle sipo aarẹ mọ ju saa
kan lọ. O ti di mimọ bayii pe, aarẹ ilẹ yii tẹlẹri, Goodluck Jonathan, ti gbero lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC lati dije fun ipo naa lọdun
2023.
Ọgbẹni Falana waa lo ọrọ gomina ipinlẹ Ọyọ nigba kan, Rasheed Ladọja, gẹgẹ bii apẹẹrẹ lasiko to n wa ọna lati lọ fun ipo gomina lẹẹkan si i lati fi dipo akoko ti ko si lọfiisi nigba ti wọn yọ ọ nipo lọna aitọ.
O ni gbogbo akitiyan Ladọja niwaju ile-ẹjọ to ga ju
nilẹ yii lo ja si pabo, oun ti wọn sọ fun un ni pe iye ọdun ti gomina le lo lori iṣejọba ko ju ọdun mẹjọ lọ, afi ti ko ba tun ni i pe ọdun mẹjọ ọhun lo ku.
Falana waa pari ọrọ ẹ pe ofin ko le gba ẹnikẹni laaye lati wa lori aleefa ju ọdun mẹjọ lọ lapapọ.

Leave a Reply