Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Aya aarẹ orileede yii, Arabinrin Olurẹmi Tinubu, ti sọ pe itara ti oun ni si ọrọ awọn obinrin ati ọrọ ẹkọ to peye fun awọn ọdọbinrin lo fa a ti oun fi ṣedasilẹ ileewe kan ti wọn pe ni Alternative High School for Girls.
Nigba to n ṣefilọlẹ ileewe naa ti wọn fẹẹ kọ si agbegbe D. O, ni Oke Ayépé, niluu Oṣogbo, lọjọ Iṣẹgun,Tusidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu yii, ni Rẹmi Tinubu sọ pe ileewe naa yoo wa fawọn ọdọbinrin ti wọn ko lanfaani lati tẹsiwaju ninu ẹkọ wọn.
O ni pupọ ọdọbinrin lo jẹ pe ti wọn ba ti gboyun tabi ti nnkan kan ṣelẹ si ni wọn ko ni i lanfaani lati tẹsiwaju ninu ẹkọ wọn, eleyii ti yoo dabaru iran rere ti wọn ni fun ọjọ iwaju ara wọn.
Olurẹmi ṣalaye pe lẹyin ti wọn yi koto (raffle) laarin awọn iyawo gomina kaakiri orileede yii ni wọn mu ipinlẹ Ọṣun gẹgẹ bii ibi ti wọn fẹẹ kọ ileewe naa si.
Nipasẹ ileewe naa, Tinubu ni ide aini, ope (ignorance) ati aidọgba yoo ja patapata lawujọ wa nigba to ba di pe gbogbo awọn obinrin, paapaa, ọdọbinrin, lanfaani si nnkan amuṣagbara ti wọn yoo fi le da duro.
Ṣaaju ninu ọrọ rẹ, Gomina Ademọla Adeleke dupẹ lọwọ aya aarẹ fun wiwa to wa sipinlẹ Ọṣun fun ifilọlẹ naa, o ni gbogbo nnkan to le mu idagbasoke ati igbesi aye irọrun ba awọn obinrin nijọba oun n ṣe.
O ni laipẹ yii loun gbe igbimọ kan kalẹ lati ṣakojọ orukọ awọn obinrin ti wọn n jiya aimọdi kaakiri awọn ọgba ẹwọn to wa nipinlẹ Ọṣun, kijọba le mọ ọna lati tu wọn silẹ.
Bakan naa lo ni ijọba oun ti ṣetan lati gbogun ti ẹnikẹni to ba huwa laabi si obinrin atawọn ọmọ wẹwẹ nibikibi nipinlẹ Ọṣun