Idi ti mo fi n pariwo pe ka ṣe suuru pẹlu ọrọ awọn Fulani – Oluwoo

Florence Babaṣọla

Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti kilọ fun gbogbo awọn igi wọrọkọ laaarin awọn ẹya Fulani darandaran ti wọn n fojoojumọ da wahala silẹ lorileede yii lati ti ọwọ ọmọ wọn b’ọṣọ, ki wọn si mọ pe ẹmi ko laarọ.

Bakan naa ni Oluwoo parọwa si gbogbo awọn iran Yoruba lati sinmi agbaja, ki wọn dẹkun lilu ilu ogun kaakiri nitori ko sẹni ti ko mọ pe o fi sibi kan ju ibi kan lo.

Ninu atẹjade kan ti kabiesi fi sita nipasẹ Akọwe iroyin rẹ, Alli Ibraheem, o ni oun ko deede maa lọgun lojoojumọ pe ki iran Yoruba kiyesara lori ọrọ wahala pẹlu Fulani.

O ni awọn Fulani jẹ ẹya kan lara iran Fulani, wọn si ti fọn kaakiri orileede yii, nnkan ini kan ṣoṣo ti wọn si ni ni maaluu ti wọn n ko kaakiri eleyii ti ko si to lati fi ṣakawe dukia iyebiye ti awọn ẹya Yoruba ti wọn wa nilẹ Hausa ni.

Ọba Akanbi fi kun ọrọ rẹ pe ko si ẹni to le fara mọ gbogbo iwa iṣekupani, ijinigbe, ifipabanilopọ ti awọn kọlọransi kan lara awọn Fulani n hu nitori ko bojumu rara, ṣugbọn a ko gbọdọ ro didun ifọn, ka họra deegun, a gbọdọ mọ iru awọn ti a fẹẹ ba ja gan-an.

Ọba alaye yii ni kikede ogun pẹlu awọn Fulani lewu pupọ nitori ṣe lo maa da bii ẹni pe gbogbo iran Hausa ni Yoruba fẹẹ dojukọ, o ni ti eleyii ba si ṣẹlẹ, iran Yoruba ni yoo jiya to ju nibẹ.

Oluwoo ni ko sẹni to ru epo pupa sori ti yoo maa ba oniyangi ja. O ni ko sẹni ti ko ni i ronu daadaa ko too ba awọn eeyan to jẹ pe maaluu ati ahere nikan ni nnkan ini wọn ja.

Bakan naa ni Oluwoo rọ gbogbo awọn ẹṣọ alaabo lati ri i daju pe wọn ṣedajọ ẹnikẹni tọwọ ba tẹ pe o huwa buburu lai fi ti ẹya tabi iran to ti wa ṣe, nipa ṣiṣe eleyii, kabiyesi ni awọn eeyan yoo ri i pe wọn ko gbe si ẹya kan lẹyin ju ekeji lọ.

Leave a Reply