Idi ti Tinubu fi ri Ọọni fin lode niyi o

Ademọla Adejare

Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, lawọn eeyan kọkọ bẹrẹ si i bu nigba ti fidio iṣẹlẹ naa jade, ti wọn ri ibi ti Ọọni ti n ki Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu nibi ayẹyẹ igbade Ọba Oniru, ṣugbọn ti aṣaaju ẹgbẹ APC naa jokoo soju kan nibẹ, to ki Ọọni bii igba to n ki ọkan ninu awọn ọmọ ẹyin rẹ lasan. Ko dide bi gbogbo awọn to ku ti dide, bẹẹ ni ko ṣe bii ẹni to ni ọwọ kankan fun aṣaaju Ọba ilẹ Yoruba naa. Ohun ti awọn eeyan ro ti wọn fi bu Ọọni ni pe, wọn ro pe ibi to jokoo si ni Ọọni ti dide ni aaye tirẹ to si lọọ ki i, wọn ni Ọọni lo fi ara rẹ wọlẹ, pe ko yẹ ko de ọdọ rẹ ki i rara. Ṣugbọn nigba ti wọn ju fidio naa sita daadaa, gbogbo eeyan ri i pe ọrọ naa ko ri bẹẹ, Ọọni n bọ ni tirẹ ni, bo si ti wọle ni ọpọlọpọ awọn to wa nibẹ dide duro lati yẹ ẹ si, gẹgẹ bii olori ilẹ Oodua, nibi ti gbogbo Yoruba ti wa. Ṣugbọn Tinubu ko dide.

Nigba to si jẹ ẹgbẹ Tinubu ni Ọọni yoo gba kọja lati lọọ jokoo sibi ti wọn fi aaye rẹ silẹ fun un, o di dandan fun un lati ki Tinubu nibi to wa, ṣugbọn kiki to ki ọkunrin yii lo da nnkan silẹ, nitori ọga awọn oloṣelu Eko naa gboju si ẹgbẹ kan ni, o si ki Ọba yii bii ẹni to ni ohun ti yoo gba lọwọ rẹ. Eleyii fa ibinu ọpọlọpọ eeyan ni ilẹ Yoruba, paapaa awọn ti wọn jẹ aṣaaju nibi gbogbo. Ohun ti wọn n wi ni pe arifin bẹẹ ko tọ si Ọọni, ko yẹ ko jẹ Tinubu ni yoo ṣe iru rẹ fun ọba ilẹ Yoruba, nitori aṣaaju loun naa, o si gbọdọ mọ pe dandan ni lati bọwọ fun aṣa ati iṣe Yoruba, nigba to jẹ ojulowo ọmọ kaaarọ-oo-jiire loun naa i ṣe. Lati igba naa ni oriṣiiriṣii ọrọ ti n jade, nitori awọn mi-in ni ko si ohun ti ẹnikẹni le sọ si ọrọ to wa nilẹ yii, Tinubu lagbara ju Ọọni lọ nitori ipo oṣelu to di mu, gbogbo ẹni to ba si ti wa nilẹ Yoruba lo wa labẹ rẹ.

Awọn eeyan mi-in kọ eleyii ṣaa, wọn ni irọ gbuu ni. Wọn fi ti Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ ṣe apẹẹrẹ nigba aye rẹ, wọn si gbe fidio igba kan ti oun naa jokoo sibi ayẹyẹ, ti Ọọni, Ọba Okunade Ṣijuade, si wọle de. Awolọwọ dide lẹsẹkẹsẹ bi gbogbo awọn eeyan to ku nibẹ ti ṣe, bẹẹ oun ni olori ẹgbẹ oṣelu to wa nijọba, aṣẹ to ba si pa ni. Fidio naa fi han pe Awolọwọ ko ṣe bi Tinubu ti ṣe, bo si tilẹ jẹ pe o lagbara to ju ti Tinubu lọ. Nidii eyi ni awọn mi-in ṣe n sọrọ buruku si Tinubu, ti wọn n pe e ni oriṣiiriṣii orukọ. Asiko yii lawọn kan jade lati gbeja ọkunrin oloṣelu nla asiko yii naa, wọn ni ki ẹnikẹni ma da si ọrọ yii, nitori Tinubu lo mọ bi Ẹnitan ṣe di Ọọni, nitori ọkan ninu awọn ọmọlẹyin rẹ tẹlẹ ni. Awọn yii ni bi ko ba jẹ Tinubu, Ogunwusi ko ni i di Ọọni ile-Ifẹ, nigba to si jẹ oun lo fi i joye, ko le maa fun un ni ọwọ rẹpẹtẹ kan ni gbangba.

Nibi yii ni aṣiri ti tu, ti awọn mi-in si jade pe ko ri bẹẹ, Tinubu ko lọwọ si ọrọ igbade Ọọni, Ọlọrun lo kan fẹ ki ọkunrin naa di Ọọni. Ibi ti awọn eeyan ti waa n beere naa ree pe ki lo kuku de ti Tinubu ko ni ọwọ fun Ọọni Ileefẹ, ki lo de ti Tinubu ṣe bayii ri Ọba ilẹ Yoruba yii fin. Iwadii ALAROYE fihan pe ọrọ naa ko ṣẹṣẹ bẹrẹ, o ti wa nilẹ to ọjọ mẹta kan. Fun ẹni to ba ranti, iṣẹlẹ kan waye ni ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kẹrin, ọdun 2017, nibi ayẹyẹ kan niluu Eko. Ọba Riliwan Akiolu, Elekoo ilu Eko ti wa lori ijokoo, bẹẹ si ni Obi Onisha, Igwe Alfrerd Achebe. Bi Ọọni ti de lo sare lọ lati ki awọn ọba mejeeji, Ọba ilẹ Ibo naa si dide lati ki i tọyaya tọyaya, ṣugbọn bo ti ni ki oun sun mọ Akiolu bayii, niṣe ni Ọba Eko yii gbe oju rẹ si ẹgbẹ kan, to si juwọ bele lati fi han pe oun ko fẹẹ ri Ọọni, tabi ko sun mọ oun. Ọrọ yii di wahala nla.

O di wahala nla, nitori ko sẹni to lero pe ẹnikan yoo ṣe bẹẹ si Ọọni, paapaa Ọba ilu Eko, nigba ti ki i ṣe pe ija kankan ti aye gbọ nipa ẹ ti wa laarin wọn tẹlẹ. Nigba tọrọ naa di ariwo rẹpẹtẹ lori ẹrọ ayelujara, ti oniwa n bu u, ti ẹlẹyin n bu u, ti wọn saa n sọ pe ohun ti ọba yii ṣe ko daa, Ọba Eko jade sọrọ, o ni oun ko ri Ọọni fin, ọun ko si fi i wọlẹ, bi awọn ṣe maa n ki ara awọn ni Eko, ti awọn maa n juwọ si ara awọn loun ṣe fun un, awọn ki i di mọ ara awọn l’Ekoo, nitori ẹ loun ko ṣe jẹ ki Ọọni di mọ oun. Gbogbo eeyan lo mọ pe irọ gbuu lọrọ ọba naa, wọn si gbe aworan awọn ibi ti oun ati awọn ọba mi-in, ati awọn oloṣelu ti n bọwọ, ti wọn n di mọ ara wọn jade. Ọrọ naa lọ bẹẹ, ṣugbọn awọn ti wọn ni ọgbọn ko yee fiye si i. Alaye ọrọ naa ṣẹṣẹ waa jade wayi, iyẹn leyi ti Tinubu ṣe yii, to ṣe l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja yii.

Ohun to fa ibinu Akiolu nijọsi, to si tun fa ti Aṣiwaju yii ni pe wọn ko fẹran bi ero rẹpẹtẹ ti maa n ba Ọọni wọle nibikibi to ba lọ fun ayẹyẹ. Wọn ti sọ ọrọ naa laarin ara wọn titi, pe nigba ti Ọọni ba ti n bọ nibi kan, oun ni yoo gbẹyin debẹ, ko si too wọle ni awọn ẹmẹwa aafin rẹ yoo ti sare wọle, ti wọn yoo pariwo pe Ọọni n bọ, Ọọni n bọ o, ti gbogbo eeyan yoo si dide fun un. Bi awọn yii ti n ṣe bẹẹ, bẹẹ ni awọn kan yoo ti sare, ti wọn yoo lọ si ibi ti yoo jokoo si, ti wọn yoo si fi aṣọ funfun ti wọn wọ gba ori aga naa. Ni gbogbo akoko ti wọn ba n ṣe eyi, ko si ẹlomiiran ti yoo tun gba iyi ju Ọọni lọ, ọdọ rẹ nikan ni gbogbo oju awọn eeyan to wa nibẹ yoo wa, oun ni wọn yoo maa wo bii iran. Eleyii ko dun mọ Ọba Eko ninu, bo si jẹ awọn ọba mi-in ati aṣaaju oloṣelu Eko naa n binu, Akiolu lo kọkọ fi han ni gbangba, ọrọ oun ati Tinubu si bara mu lori Ọọni.

Ṣugbọn ibinu ti Tinubu tun lọ siwaju diẹ ju eleyii lọ. Nigba ti Ọba Okunade Ṣijuwade waja ni ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu keje, ọdun 2015, ọkan ninu awọn ti wọn fẹẹ du ipo lati bọ si ori oye yii ni Ẹnitian Ogunwusi, nitori ti oun naa si mọ pe ero pọ lori ipo naa, o lọọ ba ọrẹ rẹ kan sọrọ, iyẹn Ọba Saheed Ademọla Ẹlẹgushi, nitori awọn mejeeji jọ ni awọn okoowo ti wọn n ṣe pọ. Nigba ti wọn de ọdọ Tinubu ti wọn si sọ ohun ti wọn ba wa, Aṣiwaju ko fi ọrọ pe meji, o wo oju Ẹnitan Adeyẹye, o si sọ fun un pe ko le jẹ Ọọni, ko kuro nibẹ, awọn to fẹẹ jẹ kinni naa ti wa, ko si eyi to kan an ninu rẹ rara. Ohun to ṣẹlẹ ni pe Tinubu ni awọn ọrẹ tirẹ to fẹ ki wọn di Ọọni. Ẹni kan lo ni lọkan tẹlẹ, ṣugbọn nitori pe iyẹn ko fẹ kinni ọhun, o sa lọ kuro nile, o si lọ siluu oyinbo lai ba wọn da si i. Tinubu tun nawọ mu ẹlomi-in, ṣugbọn iyẹn naa tun ja bọ. Nigba naa ni awọn agbaagba Ifẹ gbọ ohun to n lọ, wọn si pinnu pe ki ṣe Tinubu ni yoo fi Ọọni jẹ fawọn.

Bayii ni awọn ara Ifẹ gbe nnkan gbẹyin Tinubu, nigba tọrọ naa si de iwaju Gomina Raufu Arẹgbẹṣọla igba naa, o sọ fun ọga rẹ pe ti awọn ko ba fẹ wahala ni Ileefẹ yii, afi ki wọn fi ẹni ti awọn araalu mu naa silẹ o. Lati igba naa ni ọrọ oun ati ti Ọọni ti ni mẹbẹmẹyẹ ninu, nitori bi oun naa ko ti fẹran Adeyẹye Ẹnitan gẹgẹ bii Ọọni, ko jọ pe Ọba Ogunwusi fẹran rẹ bii aṣaaju Yoruba, Igba kan wa ti Tinubu dẹ awọn eeyan si Ọọni pe oye ti Awolọwọ jẹ ni Ileefẹ titi to fi ku, iyẹn oye Ọdọle, pe ki wọn fi Tinubu jẹ ẹ ki ija le pari. Ọọni ko dahun, kaka bẹẹ, Baba Ijẹbu, Oloye Adebutu Kessington, lo fi jẹ oye naa, eleyii si mu ija to wa laarin wọn le diẹ si i, bo tilẹ jẹ pe Tinubu ko le rojọ naa ni gbangba. Idi si niyi to jẹ bo ṣe ṣe fun Ọọni ni gan-an lọsẹ to kọja yii ko jọ awọn mi-in loju, wọn ni o lohun to n bi i ninu si Ọọni ni

7 thoughts on “Idi ti Tinubu fi ri Ọọni fin lode niyi o

  1. Hmmm Aimo iyi olorun lara oba ooni lo n da babawa tinubu lamu. Iyen niwipe olodumare nikan lolegbeyan de ipo giga kokinse eniyan. Nigbati awon tiso arawon di olorun.

Leave a Reply