Idi ti Tinubu ko fi le di aarẹ Naijiria ni 2023 ree o

Wọn ti n pana ọrọ naa bọ lati bii ọdun meji sẹyin, ṣugbọn ni bayii, ọrọ naa ti burẹkẹ, bi Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ko ba si mura daadaa, ọrọ naa yoo fa a lẹwu ya. Ohun ti awọn eeyan wa n sọ ni pe ṣe ki i ṣe nitori ọrọ ibo aarẹ ọdun 2023 lawọn eeyan kan ṣe dide ti wọn fẹẹ koba Tinubu bayii, ṣugbọn awọn ti wọn mọ ipilẹ ọrọ naa ni kinni naa ki i ṣe bẹẹ, pe ohun ti Tinubu funra ẹ ti ṣe sẹyin tẹlẹ lo fẹẹ pada di wahala si i lọrun, bi ko ba si fẹsọ ṣe e, ọrọ naa yoo mu un lomi. Alaye mi-in tawọn eeyan n ṣe ni pe Tinubu wa lara awọn ti wọn tori ẹ le Ibrahim Magu, alaga EFCC tẹlẹ, lọ, nitori wọn ni Tinubu funra rẹ ti sọ pe bi Magu ba wa nipo rẹ, ko si mimi kan ti yoo mi oun. Koda ki awọn kan sopanpa ju bẹẹ lọ, ki wọn mura lati ran oun lẹwọn tabi tu aṣiri awọn ohun ti oun ṣe, ko si ohun ti wọn yoo le fi oun ṣe.

Bi ibo ọdun 2023 yii ṣe n sun mọle lawọn kan n wa ọna ti Tinubu o fi ni i jade, tabi ti wọn yoo ti di i lọwọ rẹpẹtẹ ko too di ọjọ naa, ohun tawọn ti wọn sun mọ ọkunrin oloṣelu naa si n wi ni pe iru iyẹn ko ni i ṣee ṣe. Ṣugbọn pẹlu ẹjọ buruku ti wọn hu jade bayii, ti ọrọ naa si ti di ti ile-ẹjọ, ti wọn si ti paṣẹ pe afi ki Tinubu yọju si ile-ẹjọ naa ko waa wi tẹnu ẹ, ko si bi ọrọ naa ko ṣe ni i di ariwo, bẹẹ ni ko si bi ẹjọ naa ko ṣe ni i ko ba Tinubu. Ọkunrin kan lo ti ọpa bọ isa ejo, oun lo ja ejo naa loju, o si ni ọrọ naa ti kọja ohun ti awọn le pari ni kọrọ, gbangba loju aye lawọn yoo ti yanju ẹ. Ẹni to ba mọ Tinubu ko sọ fun un ko maa mura silẹ ni, nitori ẹjọ ti yoo mi gbogbo ilu titi ni. Ọkunrin naa ti pẹjọ o, o pe Tinubu ati ileeṣẹ rẹ kan ti wọn n pe ni Alpha Beta lẹjọ, o ni ileeṣẹ naa ni Tinubu lo lati ko owo buruku, owo awọn ara Eko jẹ.

Ọrọ ti eegun ba sọ ni, ara ọrun lo sọ ọ. Ẹni to fi ẹsun kan Tinubu yii, ẹni to mọ ọn deledele ni, awọn ẹsun to si fi kan an yii, ẹsun to lagbara pupọ ni. Bi ijọba kan tabi ile-ẹjọ ba tẹra mọ ẹjọ yii, ohun ti wọn yoo kan nidii rẹ ko le dara fun aṣaaju APC naa, ati ilakaka rẹ lati di aarẹ. Dapọ Apara ni orukọ ọkunrin naa, oun si ni olori ileeṣẹ Alpha Beta fun odidi ọdun mejila gbako. Alpha Beta yii ki i ṣe ileeṣẹ kekere kan, ileeṣẹ to n ba ijọba ipinlẹ Eko gba owo-ori lati ọdun 2002, ọdun mejidinlogun sẹyin, titi di asiko ti a wa yii ni. Ṣugbọn titi di asiko ti ede-aiyede de laarin Tinubu ati Apara, ko sẹni to mọ pe Tinubu lọwọ si ileeṣẹ naa rara, ohun ti wọn n ro ni pe awọn oyinbo lo ni Alpha Beta, ati pe ijọba Eko gbe ileeṣẹ naa wa lati oke-okun lati maa waa ba awọn gba owo-ori. Owo ti wọn gba laarin asiko yii, owo nla ni.

Nigba ti ileeṣe naa kọkọ bẹrẹ, bii biliọnu mẹwaa Naira (N10billion) ni ileeeṣẹ naa n ba ijọba Eko gba wọle lọdọọdun, ṣugbọn nigba ti yoo fi di ọdun 2018, owo ti Alpha Beta n ba ijọba Eko pa le ni ọọdunrun biliọnu Naira (N300billion) laarin ọdun kan. Iye yoowu ti Alpha Beta ba waa pa bayii, ida mẹwaa ni tiwọn ninu owo naa. Eyi ni pe bi wọn ba pa ọgọrun-un biliọnu fun ijọba, biliọnu mẹwaa ni tiwọn nibẹ, owo naa si maa n le ju bẹẹ lọ nigba mi-in; bi wọn ba pa ọọdunrun biliọnu, awọn yoo mu ọgbọn biliọnu nibẹ lai duro de ẹnikẹni, owo naa si le ju bẹẹ lọ. Nidii eyi, ọkan ninu awọn ileeṣẹ to n ṣowo, to n jere, julọ ni Naijiria, ti owo naa ko si bajẹ lati bii ọdun mejidinlogun bayii ni Alpha Beta n ṣe.

Bi ileeṣẹ yii ti waa n pa owo to yii, awọn iwa kan wa ti ileeṣẹ naa n hu ti ko dara. Akọkọ ni pe ileeṣẹ naa ki i san owo-ori to yẹ ki wọn san pada si apo ijọba, bakan naa ni wọn n lo ileeṣẹ naa lati ko owo buruku lọ si oke-okun, ileeṣẹ yii si tun n lu ijọba ni jibiti owo to pọ gan-an. Ko si ẹni meji to tu aṣiri eyi ju Apara funra ẹ lọ, nitori ko sẹni to le mọ aṣiri ileeṣẹ naa ju Apara yii lọ. Idi ni pe gẹgẹ bi akọsilẹ ti wi, ki i ṣe pe ileeṣẹ naa deede lalẹ hu, Apara ni oun funra oun loun ronu nipa ileeṣẹ naa, ti oun gẹgẹ bii oluṣiro-owo ati agbowoka agba ro o lọkan ara oun pe o ṣee ṣe ki ijọba Eko maa fi ẹrọ ayara-bi-aṣa gba owo-ori awọn eeyan ipinlẹ wọn, lẹyin ti oun si ti ro ọrọ naa ni arogun ni oun gbe e lọ sọdọ ijọba Eko lọdun 2000 pe ki wọn jẹ ki oun waa maa ba wọn ṣiṣẹ naa, ki wọn si maa fun oun ni ohun to ba tọ soun.

Apara ni orukọ ileeṣẹ oun ti oun fẹẹ maa fi ṣiṣẹ yii nigba naa ni ‘Infiniti Systems Enterprise’, orukọ yii loun si fi gbe iṣẹ naa lọ sọdọ awọn Tinubu. O ni nigba ti Tinubu ri iwe iṣẹ ti oun kọ lọ, o ranṣẹ soun, nitori oun ni gomina Eko nigba naa. Nibi ipade awọn ni Tinubu ti sọ pe bi oun Apara ba fẹ ki ijọba Eko gbe iṣẹ naa foun, a jẹ pe awọn yoo tun iwe naa ṣe lorukọ ileeṣẹ mi-in ni o, pe awọn yoo da ileeṣẹ tuntun silẹ, ileeṣẹ ti awọn ba si da silẹ yii ni yoo maa gbe iṣẹ naa jade lati ọdọ ijọba ipinlẹ Eko. Ṣugbọn ki i ṣe Apara nikan ni yoo da ni ileeṣẹ naa, oun ati Tinubu funra ẹ ni. Tinubu ni ninu ipin-okoowo (Shares) ọgorun-un ti ileeṣẹ naa ba ni, Apara yoo mu iko ọgbọn (30 per cent), oun Tinubu yoo si ni aadọrin (70 per cent) to ku. Ṣugbọn oun Tinubu ko ni i fi orukọ oun si ileeṣẹ naa, orukọ awọn aṣoju kan loun yoo fi si i.

Apara ni Tinubu fẹnu ara rẹ sọ foun pe oun ko le fi orukọ oun si i, ki ajọ to n tọpinpin owo awọn oṣiṣẹ ijọba ma le maa le oun kiri, tabi ki wọn maa tudii oun wo to ba ya. Apara gba ọrọ ti Tinubu sọ gẹgẹ bii gomina, inu rẹ si dun pe oun ri eeyan nla ba ṣe, ati pe iṣẹ ti oun mọ lọkan lati ṣe fun ijọba ipinlẹ Eko yoo ṣee ṣe. Bayii ni wọn fi orukọ ileeṣẹ Alpha Beta silẹ ninu iwe ijọba, wọn si pe orukọ ileeṣẹ naa ni Alpha Beta Consulting Company Limited. Ninu ipin idokoowo naa, gẹgẹ bi adehun ti wọn ti ṣe tẹlẹ,  Dapọ Apara ni ọgbọn, Tinubu si ni aadọrin. ṢugbọnTinubu ko fi orukọ ara rẹ si i, o mu ọkunrin kan, Olumide Ogunmọla, wa, bo si tilẹ jẹ pe Apara ko mọ tọhun tẹlẹ, lẹyin ti Tinubu ti mu wọn mọ ara wọn, oun ni Tinubu ni ki wọn fun ni ipin ogoji (40 per cent), bẹẹ ni ki Apara fun Adegboyega Oyetọla, ẹni to jẹ gomina ipinlẹ Ọṣun bayii, to si jẹ ibatan Tinubu, ni ipin ọgbọn.

Bayii ni ileeṣẹ Alpha Beta bẹrẹ iṣẹ. Ko pẹ ti iṣẹ naa n lọ ti Tinubu paṣẹ fun Apara pe ko lọọ yọ orukọ Adegboyega Oyetọla kuro ninu iwe naa, ko si fi ti Tunde Badejọ rọpo rẹ, Apara si ṣe bi Tinubu ti wi gan-an. Bayii lo jẹ lati igba naa, orukọ awọn mẹta ti wọn ni ileeṣẹ Alpha Beta yii ni Dapọ Apara, Olumide Ogunmọla ati Tunde Badejọ, ṣugbọnTinubu lawọn mejeeji ti wọn gbẹyin yii n ṣiṣẹ fun.  Bi ẹni meji yoo ba fi ọwọ si owo ti wọn ba fẹẹ gba jade lati banki, Dapọ Apara ati ẹni kan ninu awọn meji to ku yii ni, bi Dapọ Apara ko si fi ọwọ si iwe owo naa, yoo ṣoro ki owo too jade, nitori oun gan-an ni oludari agba fun ileeṣeẹ wọn. Lẹyin ti wọn ti fi ọdun mẹwaa ṣiṣẹ naa, nnkan bẹrẹ si i yipada, ko jọ pe awọn Tinubu fẹ Apara nipo ọga mọ. Igbesẹ akọkọ ni pe ijọba ipinlẹ Eko ṣe ofin kan, ofin naa si ni Tinubu lo lati pe ki wọn sọ ileeṣẹ naa di ti ọlọpọ eeyan, ṣugbọn pẹlu ẹ naa, ko sẹni kan ti wọn gba orukọ ẹ wọle ju tawọn to ti wa tẹlẹ lọ.

Ohun ti Tinubu lo eto naa fun ni lati fi Ogunmọla ṣe olori ileeṣẹ Alpha Beta, iyẹn lati dọgbọn gba ipo olori naa kuro lọwọ Apara. O ni ki Ogunmọla jẹ olori, nigba to jẹ aṣoju oun Tinubu ni, to si jẹ oun Tinubu ni oun ni ipin-idokoowo to pọ ju lọ nileeṣẹ ọhun, ki Apara si jẹ igbakeji rẹ. Nigba to tun di ọdun 2014, nnkan tun fẹẹ daru laarin Ogunmọla ati Tinubu, Tinubu si tun paṣẹ pe ki Ogunmọla fi ipo olori ileeṣẹ naa silẹ, ki oun jẹ igbakeji, ki Apara si tun pada si ipo gẹgẹ bii ọga agba pata. Bi nnkan ṣe wa niyi titi ti ijọba Ambọde fi de ni 2015, ti nnkan si bẹrẹ si yipada, o da bii pe Ambọde fẹẹ tọwọ bọ iṣẹ Alpha Beta, o fẹẹ mọ ohun to n lọ nibẹ gan-an. Idi ni pe owo ti ijọba Eko n san fun Alpa Beta pọ pupọ ni ọdun kan, to si jẹ bi owo ti n wọle fun ijọba Eko, bẹẹ ni owo Alpha Beta n pọ si i, eyi si jẹ ohun tijọba tuntun yii fẹẹ yẹwo.

Ṣe oluṣiro owo agba ni Ambọde nileeṣẹ ijọba Eko ko too fẹyinti, o si mọ nipa Alpha Beta yii ati owo buruku ti wọn n gba lọwọ ijọba wọn. Nidii eyi, o jọ pe o fẹẹ gba iṣẹ naa kuro lọwọ Tinubu ati Alpha Beta rẹ, ki eleyii ma si ṣe ri bẹẹ ni Apara fi rin mọ Ambọde, to si mura lati ṣe ohun ti ọkunrin gomina tuntun naa ba ni ki wọn ṣe, ki wọn ma le gba iṣẹ ti wọn n ṣe naa lọwọ wọn, nigba to jẹ oun Apara ni olori ati oludasilẹ ileeṣẹ yii gan-an. Ko jọ pe irin ti Apara rin sun mọ awọn Ambọde yii tẹ Tinubu lọrun rara, o si mura lati igba naa lati gba gbogbo agbara ti Apara ni kuro lọwọ rẹ, o fẹẹ yọ ọ nipo ọga, bo ba si ṣee ṣe, ko yọ orukọ rẹ kuro ninu iwe ileeṣẹ naa, ṣugbọn eleyii ṣoro pupọ lati ṣe, nigba to jẹ Apara lo fi orukọ ileeṣẹ naa silẹ ninu iwe ijọba,ko si si ẹni to le ṣe ohunkohun lẹyin rẹ nibẹ, ṣe akauntanti loun naa.

Nigba naa ni Tinubu kede fun Apara pe yoo fi ipo oga silẹ, oun si n gbe ẹlomi-in bọ ti yoo waa jẹ olori pata fun ileeṣẹ naa, ẹni ti yoo jẹ olori fun ileeṣẹ yii ni Akin Doherty. Ni gbogbo igba ti Tinubu n ṣe gomina, ọkan ninu awọn kọmiṣanna rẹ ni Doherty yii n ṣe, koda, oun ni kọmiṣanna fun eto inawo ninu ijọba Tinubu titi di ọdun 2007 ti wọn gbejọba silẹ. Ojulowo ọmọ Tinubu ni. Oun ni Tinubu mu wa pe ko waa gba ipo olori ati ọga agba ileeṣẹ naa, pe Apara yoo si jẹ igbakeji rẹ, ti wọn yoo jọ maa ṣe. Ẹsun ti wọn fi kan Apara nigba naa ni pe o n tọwọ bọ iwe owo, o n wadii awọn owo ti ileeṣẹ naa ti pa lati ẹyin ati bi wọn ti na awọn owo yii si, iyẹn ni gbogbo asiko to fi jẹ oun kọ ni ọga agba fun ileeṣẹ wọn. Wọn ni o fẹẹ lo iwe naa lati fi tu aṣiri owo ti ileeṣẹ naa na fun ijọba Ambọde ni. Bẹẹ, wọn si mọ laarin ara wọn pe Ambọde naa fẹẹ da ileeṣẹ bii ti Alpha Beta silẹ, ko le maa gba iru owo ti Tinubu n gba ni.

Ọrọ yii bi Apara ninu wayi, pe bawo ni ẹni ti ko mọ igba ti awọn da ileeṣẹ silẹ yoo ṣe wa maa sẹ ọga le oun lori, ti wọn si tun waa paṣẹ pe oun ko gbọdọ mọ bi wọn ti nawo ileeṣẹ naa, oun ko si gbọdọ wadii bi owo ba ti ṣe n jade. Eyi lo sọ loju awọn eeyan, ti awọn yẹn si gbe ọrọ naa lọọ ba Tinubu, ti Tinubu fi ranṣẹ si i, to si sọ loju rẹ pe bi oun ti ṣe fẹẹ ṣe ileeṣẹ oun loun n ṣe e yẹn, nitori ileeṣẹ naa ki  i ṣe tirẹ, oun loun ni ipin idokoowo to pọ ju lọ. Nigba naa ni Apara sọ pe Tinubu sọ foun pe boun ba ro pe oun le tu aṣiri oun, ti oun gbe ọrọ naa lọ si ọdọ awọn EFCC, oun kan n daamu ara oun lasan ni o, nitori ẹni to wa ni EFCC to jẹ olori wọn nibẹ, Ibrahim Magu, ọkan ninu awọn ọmọ oun ni, ko si ni i jẹ ki iru ọrọ bẹẹ jade laelae. Sibẹ naa, Apara taku, o ni oun ko ni i ṣe igbakeji fun Akin Doherty nile iṣẹ ti awọn jọ da silẹ.

Pẹlu ẹ naa, Tunde Badejọ, ọkan ninu awọn ti wọn jọ da ileeṣẹ naa silẹ, mu Akin Doherty lọ si ileeṣẹ Alpha Beta, o si fi i han awọn oṣiṣẹ ibẹ gẹgẹ bii olori ileeṣẹ wọn tuntun. Lọjọ naa, Apara ni Badejọ kilọ fun oun pe ti oun ba fi tun fẹsẹ rin wa si ọfiisi awọn yii, oun yoo pa oun danu ni. Bi Apara ṣe kuro ni ileeṣẹ naa niyi, ti wọn si le e pe ko gbọdọ wa sibẹ mọ laelae. Ni 2018 leleyii ṣẹlẹ, Apara si sare ko gbogbo iwe to ni jọ, o jọ pe pẹlu atilẹyin Ambọde ti i ṣe gomina nigba naa ni, o si kọ ẹsun oriṣiiriṣii, bẹẹ lo tu aṣiri awọn ohun to ni Tinubu ṣe, bo ti n ko owo ileeṣẹ naa si apo ara rẹ, to n paṣẹ ki wọn maa ko owo wọn lo si oke-okun, to si n fi ileeṣẹ Alpha Beta lu ijọba Eko ni jibiti. Ọkunrin yii pa gbogbo rẹ pọ, o si kọwe naa si EFCC ninu oṣu keje, ọdun 2018, o ni ki won wadii ọrọ naa bo ba jẹ irọ loun n pa.

Ṣugbọn EFCC gba iwe naa, wọn ju u si ẹgbẹ kan, gẹgẹ bi Tinubu ti ṣe leri ni, ko sẹni kan to pe Apara tabi awọn lọọya rẹ lati waa ṣe alaye ohun kan fun wọn lori ọrọ naa, wọn ṣe bii ẹni pe awọn ko ri i. Nigba ti ọrọ naa fẹẹ maa di ariwo, ti awọn eeyan bẹrẹ si i sọ pe ki lo de ti EFCC ko wadii Tinubu lori ẹsun ti wọn fi kan an, awọn EFCC yii jade ni ọjọ keje, oṣu kẹsan-an, ọdun 2018, wọn ni loootọ lawọn ti gba iwe ti Apara kọ, awọn si ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lori rẹ, araalu yoo gbọ esi kia. Ṣugbọn titi ti ọdun 2018 fi kọja lọ, ti 2019 tẹle e, ti 2020 si fẹẹ pari bayii, ko ṣẹni to gbọ kinni kan lẹnu EFCC. Wọn tẹ ọrọ naa mọlẹ loootọ ni. Ohun to jẹ ki Apara ṣẹṣẹ waa gba ile-ẹjọ lọ bayii niyi, to ni ki awọn adajọ ba oun da a pe ki Tinubu ati ileeṣẹ Alpha Beta san owo-oṣu ati owo to kan oun gẹgẹ bii oludasilẹ ileeṣẹ Alpha Beta foun, ki ileeṣẹ si paṣẹ fun EFCC lati wadii ẹsun ti oun fi kan Tinubu ninu iwe ti oun kọ ranṣẹ si wọn.

Ile-ẹjọ giga Eko kan ni Apara ti pe ẹjọ naa, o si ti yẹ ki ẹjọ bẹrẹ, ṣugbọn gbogbo ibi ti wọn wa Tinubu de lati fun un niwee ipẹjọ ni wọn ko ti ri i. Wọn wa a de Eko, wọn lo ti jade niluu, wọn wa a de Abuja, wọn lo ti jade niluu, wọn si de ileeṣẹ Alpha Beta, ko sẹni kan to ṣetan lati gba iwe ipẹjọ naa lọwọ wọn. Lọọya ti Apara gba, Tade Ipadeọla, ti ni ko si ohun ti awọn fẹẹ ṣe bayii ju ki awọn lọọ ba ile-ẹjọ sọrọ, ki wọn le jẹ ki awọn gbe iwe ipẹjọ naa sinu beba ati awọn ibi ti awọn eeyan naa yoo ti ri i, nitori laarin ọjọ mejilelogoji ni wọn gbọdọ pade nile-ẹjọ. Ohun to han ni pe ileeṣẹ Alpha Beta ati Tinubu paapaa ko fẹ ki ọrọ naa de ile-ẹjọ, nitori ileeṣẹ naa ti jade sita pe ki i ṣe Tinubu lo kowo jẹ, tabi lo dari owo si apo ara rẹ, bo tilẹ jẹ pe Apara ko awọn iwe ati ẹri oriṣiiriṣii silẹ lati sọ ibi ti Tinubu dari owo ileeṣẹ naa si, ati awọn akaunti tirẹ ti wọn n sanwo si.

Wọn ni Apara lo kowo jẹ, iyẹn lawọn ṣe le e. Ṣugbọn lọna keji, wọn ni awọn tilẹ ti n wa a tipẹ pe ko waa jokoo ki awọn jọ sọrọ naa ni asoye, iye to ba si jẹ owo tirẹ nileeṣẹ yii, ki awọn san an fun un ko maa ba tirẹ lọ. Ṣugbọn ko jọ pe ọrọ naa yoo lọ bẹẹ, nitori ko jọ pe Apara ṣetan lati fi ileeṣẹ Alpha Beta yii silẹ fun Tinubu, o si ti sọ pe ogun biliọnu lowo oun to ti wa nilẹ bayii,ki wọn tete ba oun ko o. Ṣugbọn awọn to mọ nipa oṣelu ni ọrọ naa le ju bi awọn eeyan ti n foju wo o lọ, wọn ni idi ti yoo fi ṣoro fun Tinubu lati jade pe oun yoo di aarẹ orilẹ-ede yii niyi, nitori ọrọ to jade sita yii, bi Tinubu ko ba jawọ ninu ilakaka rẹ lati di aarẹ, afaimọ ni ko ni i wa latimọle tabi lọgba ẹwọn lasiko ti wọn yoo fi maa dibo naa, nitori ẹjọ naa yoo burẹkẹ mọ ọn lọwọ. Akọkọ ni pe bi Tinubu ba fi le jade pe oun loun ni ileeṣẹ Alpha Beta, tabi ti wọn ba ri owo kan to wọ inu akaunti rẹ lati ileeṣẹ yii, ko si ki ọrọ naa ma gbe e de ọgba ẹwọn.

Idi ni pe o lodi sofin lati wa ninu ijọba gẹgẹ bii gomina, ki tọhun si lọọ da ileeṣẹ silẹ, ko si maa fi orukọ ileeṣẹ naa gba iṣẹ lọdọ ijọba to ti n ṣe olori. Ohun ti Tinubu si fi Alpha Beta ṣe ree, nitori lati ọdun 2002 ni wọn ti n gba iṣẹ lọwọ ijọba. Lọna keji, Tinubu ko ṣalaye fun ileeṣẹ to n ṣe akọsilẹ ohun-ini awọn oloṣelu to fẹẹ ṣejọba ki wọn too bẹrẹ iṣẹ, ati lẹyin ti wọn ba pari iṣẹ naa tan, pe oun ni oun ni ileeṣẹ Alpha Beta tabi pe oun gba owo kan lọwọ wọn. Ẹsun buruku leleyii naa ninu iwe ofin ijọba, ọna ti Tinubu si fi le bọ ninu rẹ ni ko jawọ ninu pe oun fẹẹ du ipo aarẹ, bi bẹẹ kọ, ọna ti awọn ọta rẹ yoo gba fi mu un niyi. Awọn ti wọn n woye ọrọ yii ni bi ko si ohun ti ajanaku jẹ tẹlẹ ikun, ko le ṣe ikun gbentọ si ọlọdẹ, bi ko ba jẹ Apara ni awọn alatilẹyin kan ni, ko le gbe iru ẹjọ yii jade, nigba to mọ pe o ṣee ṣe ki ẹjọ naa ko ba oun gan-an alara.

Awọn Tinubu naa n wa ọkunrin yii karakara, ṣugbọn o ti sa mọ wọn lọwọ, ko si sẹni to mọ ibi to sa si, o jọ pe nigba ti ẹjọ naa ba de oju rẹ ni yoo too jade. Afaimọ ko ma jẹ ibi yii ni awọn alatako Jaganban yoo gba yọ si i, ti yoo si ṣoro fun un lati jade pe oun yoo du ipo aarẹ lọdun 2023. Bi ko ba si du ipo aarẹ, ko si bi yoo ti ṣe di aarẹ Naijiria ni 2023

5 thoughts on “Idi ti Tinubu ko fi le di aarẹ Naijiria ni 2023 ree o

  1. E lo joko jee, Ki gan an no ede to Bola Tinubu se, to Awon kan ko ti i se ri ?, Ta ni yoo wa niru IPO Tinubu to Lola, Ti ti e O ni bury ju ti Bola Tinubu lo?, Ofo to nse Orile ede Nigeria no Ojo to pe, Ko sese bere, BOLA TINUBU se gomina saa meji Olodunejo Leko, Ko si mi IPO kankan latin 2003, Sugbon Awon to won ko se Gomina nigba naa so wa ni Ile Igbimo asofin agba (Senate) Labuja doni, Iru bio Alh Abdulahi Adamu Lati Nasarawa, Sanni Yerima Zamfara, ati Awon Miran, Sugbon Tinubu joko seko gege bi baba isale tabi afobaje Leko n bo nikan, Ki ni ese Bola Tinubu ninu gbogbo eleyi ?, Nkan aburu ti Awon miran fi nse Orile ede Nigeria lowo buru ju esun to won fi kan Bola Hammed Tinubu lo, Emi ro gbogbo Iran Omo Yoruba Lati je ki a gbaruku to Bola Tinubu Lati di Are Orile ede Nigeria lodun 2023 .

Leave a Reply