Idibo gomina n lọ lọwọ l’Ọṣun, Arẹgbẹṣọla gba ilu oyinbo lọ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Pẹlu bi idibo gomina ipinlẹ Ọṣun ṣe n lọ lọwọlọwọ bayii, iroyin ti fi han pe Minisita fun ọrọ abẹle lorileede yii, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, ko wa sile lati dibo.

Arẹgbẹṣọla, ẹni ti orukọ rẹ wa ni nọmba ọtalelugba o din mẹwaa lori akọsilẹ awọn oludibo ti ajọ INEC lẹ mọ Ifọfin, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ileṣa, lo ja pupọ awọn ọmọlẹyin rẹ kulẹ pẹlu aiwaa rẹ.

 

Nigba ti Alaroye debẹ, bi awọn kan ṣe n sọ pe ki i ṣe iru Arẹgbẹṣọla atawọn mọlẹbi rẹ ni ko yẹ ki wọn ma farahan l’Ọṣun lonii, lawọn kan ṣi n ni igbagbọ pe yoo wa.

Ṣugbọn a hu u gbọ pe ọkunrin oloṣelu naa ko si nile, orileede Germany lo wa, nibi to sọ pe oun ti lọọ ṣoju ijọba nibi iṣẹ pataki kan.

Leave a Reply