Idibo wọọdu di wahala lẹgbẹ PDP l’Ọṣun, eeyan meji ku, ọpọlọpọ fara pa

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Wahala nla lo bẹ silẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, tawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọṣun ṣeto idibo wọọdu lati yan aṣoju wọn kaakiri ijọba ibilẹ ojilelọọọdunrun un o din mẹjọ.

Idibo naa ni wọn yoo ti yan aṣoju mẹta-mẹta lati wọọdu kọọkan ni imurasilẹ fun idibo ti wọn yoo ti yan oludije funpo gomina wọn lọjọ keje, oṣu Kẹta, ọdun yii.

Ni wọọdu kẹrinla to wa ni Oke-Ọba, lagbegbe Agberire, nijọba ibilẹ Iwo, a gbọ pe wọn pa ọkunrin kan to n jẹ Toheeb Mutallib nibẹ, nigba ti wọn tun pa Arẹmu Ọlamide niluu Ipetumodu, nijọba ibilẹ Ariwa Ifẹ.

Alaroye gbọ pe iwaju sẹkiteriati ẹgbẹ PDP to wa lagbegbe Koso, niluu Ipetumodu, ni wọn ti yinbọn lu Arẹmu, ko si de ọsibitu to fi jade laye, ibinu eyi si ni wọn fi dana sun mọto Jiipu ti awọn ti wọn ṣeku pa a gbe lọ sibẹ.

A gbọ pe ọpọlọpọ eeyan ni wọn fara pa yan-na-yan-na lasiko ti awọn tọọgi n gbiyanju lati da eto idibo naa ru lawọn ijọba ibilẹ bii Ẹdẹ, Oṣogbo, Odo-Ọtin, Iwo, Ọlọrunda, Oriade ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ṣaaju ni alaga igbimọ to ṣeto idibo naa, Umaru Fintirin, ti kọkọ ṣepade pẹlu awọn oludije mẹfẹẹfa, to si parọwa fun wọn lati gba alaafia laaye, ṣugbọn wahala ni gbogbo rẹ pada yọri si.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ iṣekupani naa, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe loootọ leeyan meji ku lasiko idibo wọọdu ọhun.

Opalola ṣalaye pe ada ni wọn fi ṣa Toheeb Mutallib pa labule Agberire, niluu Iwo, nigba ti wọn yinbọn pa Arẹmu Ọlamide niluu Ipetumodu. O ni awọn eeyan mi-in ti wọn fara pa n gba itọju lọwọ nileewosan.

Ni nnkan bii aago mẹjọ aabọ alẹ ti awọn oniroyin de ibudo ti wọn yoo ti ko gbogbo esi ibo naa jọ niluu Oṣogbo, awọn agbofinro ko faaye gba ẹnikẹni lati wọle, wọn ni o digba ti Gomina Fintiri ba too fun awọn laṣẹ ki awọn to le ṣilẹkun fun ẹnikẹni.

Leave a Reply