Idris atawọn ọrẹ ẹ pa manija ileepo n’Ikire 

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Awọn afurasi mẹrin ti wọn lọwọ ninu iku manija ile-epo kan niluu Ikire, nijọba ibilẹ Irewọle, nipinlẹ Ọṣun, ni ọwọ awọn ọlọdẹ (Nigeria Hunters and Forest Security Services) ti tẹ bayii.

Gẹgẹ bi ALAROYE ṣe gbọ, ṣe lawọn afurasi naa fẹẹ lọọ jale nile-epo naa laipẹ yii, wọn si ri manija ti wọn pe orukọ rẹ ni Adigun ọhun gẹgẹ bii idiwọ, idi niyẹn ti wọn fi pa a.

A gbọ pe agbegbe Ako, niluu naa, lọwọ awọn ọlọdẹ ti wọn ti n dọdẹ wọn kaakiri ti tẹ Idris laago mọkanla alẹ ọjọ Aiku, Satide, ọjọ kẹta, oṣu Kẹsan-an yii.

Lẹyin tọwọ tẹ Idris lo jẹwọ pe awọn mẹfa lawọn jọ ṣiṣẹ naa, ati pe irin nla kan lawọn jan mọ Adigun lori lasiko ti awọn fẹẹ jale nileepo ọhun.

Nigba ti awọn ọlọdẹ ṣiṣẹ lori ijẹwọ Idris ni wọn mu awọn afurasi mẹta mi-in lọsan-an ọjọ Sannde, iyẹn ọjọ kẹrin, oṣu Kẹsan an, ọdun yii, ti wọn si fa awọn mẹrẹẹrin le awọn ọlọpaa ilu Ikire lọwọ.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe loootọ ni. O ni koda, ọwọ tun ti tẹ si i lara awọn afurasi naa ti wọn huwa yii.

Ẹru n ba mi fun Naijiria yii tori awọn ta a jọ n gbe mura ati pa wa run-Kollington

Emi nikan lọkunrin, ẹkun niyaa mi sun wa s’Ekoo nigba to gbọ pe mo darapọ mọsẹ ṣọja-Kollington

 

Leave a Reply