Idunnu ṣubu layọ ni Yunifasiti Eko, nigba ti Ọjọgbọn Ogundipẹ bẹrẹ iṣẹ pada

JIde Alabi

Pẹlu idunnu lawọn oṣiṣẹ Yunifasiti Eko, UNILAG, fi ki Olori ileewe giga naa, Ọjọgbọn Ọlọruntoyin Ogundipẹ, kaabọ pada, lẹyin ti Aarẹ Buhari ti paṣe wi pe ko maa ba iṣẹ ẹ lọ.

Bawọn oṣiṣẹ ileewe giga ọhun ti foju kan an lonijo ti n jo, ti awọn to le kọrin naa n forin dupẹ fun Ọlọrun lori bi ọkunrin naa ṣe jajabọ lẹyin ti igbimọ kan ti sọ pe ko kuro lori aga ọga agba Yunifasiti yii.

Ninu ọrọ Ogundipẹ, o dupẹ lọwọ gbogbo wọn, paapaa Aarẹ Muhammed Buhari to ṣeto bo ṣe pada sipo ẹ. Bakan naa lo sọ pe asiko niyi fun awọn oṣiṣẹ ileewe naa lati fọwọsowopọ pẹlu oun lati mu ileewe naa tẹ siwaju.

O ni, ”Ẹ je ki a jumọ fọwọsowọpọ, ki gbogbo wa si wa ni iṣọkan, ati awa ti a n kọ ni lẹkọọ atawọn oṣiṣẹ yooku pata, ọkan ni wa, a si gbọdọ jọ wa bi UNILAG yoo ṣe tẹ siwaju ni. Ki a si gba alaafia laaye ninu ọgba Yunifasiti wa.”

 

Leave a Reply