Ife-ẹyẹ idije Afrika poora ni Egypt

Oluyinka Soyemi

Ife-ẹyẹ ilẹ Afrika to wa lọwọ Egypt ti poora kuro ni olu-ile ajọ ere bọọlu ilẹ Afrika to wa ni Cairo, nilẹ Egypt.

Ṣe ni iroyin naa deede gba ilu kan lonii pe wọn ji ife-eyẹ naa, ṣugbọn Magdi Abdelghani to jẹ ọmọ igbimọ ajọ CAF sọ pe ọdun 2013 lo jona nigba ti ijamba ina kan ṣẹlẹ ni olu-ile ajọ naa.

Igbakeji Aarẹ ajọ ere bọọlu Egypt tẹlẹ, Ahmed Shobeir, ti kọkọ kede pe lasiko tawọn fẹẹ kọ ibudo ti gbogbo ife-ẹyẹ Egypt yoo wa lawọn kọkọ mọ pe kọọpu naa ti poora, ati pe lati igba naa lawọn ti n ṣewadii.

Nigba kan ni wọn sọ pe Ahmed Hassan to jẹ balogun ikọ agbabọọlu ilẹ naa lo gbe e sile, ọkunrin naa si ni oun ti da a pada, bẹẹ ni wọn tun darukọ awọn mi-in, ṣugbọn awọn yẹn pariwo pe ko si lọwọ awọn.

Tẹ o ba gbagbe, ilẹ Egypt lo gba ife-ẹyẹ ilẹ Afrika ju, igba meje ni wọn si ṣoriire naa, bẹrẹ lati ọdun 1957. Nigba ti wọn gba a leralera lọdun 2006, 2008 ati 2010 ni wọn gbe kọọpu ọhun le wọn lọwọ patapata.

Leave a Reply