Ifẹhonu han la maa fi ayẹyẹ ‘June 12’ tọdun yii ṣe- Ẹgbẹ Akẹkọọ

Faith Adebọla

Ẹgbẹ awọn akẹkọọ ilẹ wa, National Association of Nigerian Studens (NANS) ti kede pe ayẹyẹ ajọdun ijọba demokiresi ti wọn maa n ṣe lọjọ kejila, oṣu kẹfa, tọdun yii, ki i ṣe tilu-tifọn rara, iwọde ati ifẹhonu han ta ko ijọba Buhari ati eto aabo to mẹhẹ lawọn maa fi ṣe ni gbogbo ipinlẹ.

Aarẹ apapọ ẹgbẹ naa, Ọgbẹni Sunday Dare Asefọn, lo sọrọ yii fawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii.

Asefọn ni eto aabo ti dẹnu kọle debii pe awọn ọmọleewe ko le dori kọ ileewe pẹlu ifọwọsọya pe awọn maa pada sile lai sewu mọ, o lọrọ naa ti de gongo gidi.

“Ka sọrọ sibi tọrọ wa, ijọba apapọ atawọn agbofinro ti ja wa kulẹ gan-an ni, ko seyii ta a le gbẹmi-in le ninu wọn mọ.”

“Bi wọn ṣe n ji awọn ọmọleewe gbe lọgọrun-un lọgọrun-un lati bii ọdun meji sẹyin yii ti su wa, a o le maa wo ọrọ yii niran mọ, tori okun ajọṣe to so wa pọ niṣọkan lo ti fẹẹ ja yii.

A maa ṣe iwọde lati ipinlẹ kan si ekeji, a fẹ kijọba apapọ tete ṣeto apero tawọn agbaagba ti maa fori kori, ki wọn si wa ojuutu gidi si iṣoro yii, konikaluku sọ ero ati ifẹ ọkan rẹ jade.

A tun fẹ kijọba apapọ kede titi ilẹkun gbogbo awọn ileewe to wa lagbegbe Oke-Ọya pa ni saa yii na, titi ti wọn fi maa pese aabo to muna doko sibẹ.

Leave a Reply