Iku Bamiṣe: Ọbasa fọkan awọn mọlẹbi balẹ, o ni idajọ ododo maa waye

Faith Adebọla, Eko

Olori awọn aṣofin Eko, Ọmọwe Mudashiru Ajayi Ọbasa, ti fọkan awọn mọlẹbi Oloogbe Bamiṣe Ayanwọla, ati gbogbo araalu lọkan balẹ pe ileegbimọ aṣofin naa yoo gbe gbogbo igbesẹ to ba wa ni ikapa rẹ lati ri i daju pe idajọ ododo waye laipẹ lori iku ẹni wọn, ti wọn da ẹmi rẹ legbodo, Oluwabamiṣe.

Ọbasa sọrọ idaniloju yii lọjọ Iṣẹgun, Tuside, ọjọ kẹjọ, oṣu Keji yii, lasiko tawọn mọlẹbi ati ololufẹ ọmọbinrin ẹni ọdun mejilelogun naa lọọ fẹhonu han lori iṣẹlẹ ibanujẹ ọhun nileegbimọ aṣofin Eko to wa ni Alausa, Ikẹja.

Bamiṣe lawọn amookun-ṣika ẹda kan da ẹmi rẹ loro, nigba to wọ bọọsi ijọba, BRT, ni ibudokọ Chevron, l’Erekuṣu Eko, lẹyin to ṣiwọ iṣẹ lọjọ Satide, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Keji, to kọja yii. Ilu Oṣodi lo loun n lọ, ṣugbọn to dẹni awati lati ọjọ naa titi tawọn olubi ẹda kan fi lọọ ju oku ọmọbinrin ọhun sori biriiji Carter, nitosi adugbo Ogogoro, l’Erekuṣu Eko, ti wọn si ṣe bẹẹ sọko ibanujẹ nla sinu idile naa.

Niṣe ni ẹkun n pe ẹkun ran niṣẹ lasiko ifẹhonu han naa. Ọgbẹni Ayọ Ademiluyi to jẹ agbẹjọro fun mọlẹbi oloogbe sọ pe lajori idi tawọn fi wa sile aṣofin naa ni lati bẹ awọn aṣofin, ki wọn lo ipo ati agbara wọn lati ma ṣe jẹ ki oloogbe naa ku lasan bẹẹ. Wọn lawọn fẹ ki idajọ ododo waye, ki wọn si foju awọn odoro ẹda to wa lẹyin iṣẹlẹ yii han laipẹ.

“A fẹ ko ṣe kedere si yin pe iṣẹlẹ yii ki i ṣe ọrọ bintin nipinlẹ Eko, a fẹ idajọ ododo. A fẹ kẹyin aṣofin Eko tete ba wa kona mọ iwadii tawọn agbofinro yoo ṣe, bo tilẹ jẹ pe a ri i pe wọn ti mu dẹrẹba ọkọ BRT tọrọ yii kan.

“A tun fẹ ki ọga agba oluṣayẹwo iṣegun nipinlẹ Eko, Ọjọgbọn John Ọbafunwa, ṣayẹwo si oku ọmọbinrin yii, ko wọn si sọ pato ohun to ṣẹlẹ si i. A o fẹ kawọn to da ẹmi ẹ legbodo ri oorun asunwọra sun mọ laye wọn.”

Nigba to n fesi, Ọbasa kẹdun gidigidi lori iṣẹlẹ ibanujẹ yii, o si ṣadura pe Ọlọrun yoo bu ororo itura sọkan awọn mọlẹbi oloogbe naa. O loun gboṣuba fun wọn fun iwa pẹlẹ ati amumọra tawọn olufẹhonu han naa ni, ti wọn fẹsọ ṣalaye ẹdun ọkan wọn, ti wọn si ṣewọde wọọrọwọ.

“Mi o fẹ kẹ ẹ lero odi pe ijọba maa dọwọ bo ọrọ yii lori, a o ni i jẹ kiru ẹ waye. Gbogbo iwadii lori iṣẹlẹ yii la maa fun lakiyesi titi ti idajọ ododo yoo fi waye lori ẹ.

“Ileegbimọ aṣofin Eko, gẹgẹ bii aṣoju araalu, ojuṣe wa ni lati ri i pe aabo wa fun ẹni kọọkan to n gbe niluu Eko. Mo rọ wa, ka ma ti i da ẹnikẹni lẹbi titi tiwadii yoo fi pari lori ọrọ yii laipẹ. Gbogbo ohun to ṣokunkun la maa fihan kedere, idajọ ododo yoo si waye.”

Bẹẹ l’Ọbasa sọ.

Leave a Reply