Igbakeji gomina bẹ awọn eeyan Ikire, lẹyin ti wọn kọ lu ọba, ti wọn tun dana sun mọto awọn ṣọja

Jide Alabi

Igbakeji gomina ipinlẹ Ọṣun, Benedict Alabi, ẹni ti ṣe ọmọ bibi ilu Ikire, nijọba ibilẹ Irewọle, ti bẹ awọn eeyan ilu ẹ, ki wọn gba alaafia laaye, paapaa awọn ikọ mejeeji ti wọn n ja si ipo ọba ilu naa.

Ninu atẹjade ti akọwe rẹ fi sita lo ti bu ẹnu atẹ lu bi rogbodiyan ṣe bẹ silẹ ninu ilu naa, ninu eyi ti awọn eeyan kan ti inu buruku n bi, ti dana sun mọto awọn ṣọja ti wọn waa pẹtu si aawọ to n ṣẹlẹ ninu ilu naa.

ALAROYE gbọ pe ṣadeede ni wahala ọhun bẹ silẹ lori idajọ ti ile-ẹjọ to ga ju lọ lorilẹ-ede yii gbe kalẹ pe ki ọba ilu naa, Akire ti Ikire, ba Olatunde Falabi, fi ipo silẹ, ṣugbọn ti ko ṣe bẹẹ.

Wọn ni aitẹle ofin ile-ẹjọ yii gan-an lo bi awọn ọdọ kan ninu, ti wọn fi kọ lu ọba alaye yii pẹlu awọn ijoye ẹ laafin lasiko ipade wọn lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹwaa, ti wọn si sare gbe kabiesi digbadigba jade, nigba ti ọrọ ọhun di wahala rẹpẹtẹ.

Lẹyin ti wọn ti ri kabiesi gbe kuro laafin ni wahala nla yii bẹrẹ laarin awọn ọdọ ilu naa ti wọn n fẹhonu han pẹlu awọn ṣọja. Ija buruku yii ni wọn lo mu wọn dana sun mọto ṣọja, ti wọn tun lu ṣọja kan titi to fi daku mọ wọn lọwọ.

Bakan naa ni wọn tun ko ibọn meji to jẹ ti awọn ṣọja yii lọ lọjọ naa.

Igbakeji gomina yii ti sọ pe ohun idunnu lo jẹ bi Gomina Adegboyega Oyetla ṣe da sọrọ ọhun bayii, ti alaafia si ti pada siluu Ikire, l’Ọsun

.

 

Leave a Reply