Igbakeji gomina Ọṣun ṣabẹwo si abule Wasinmi ti wọn ti pa eeyan mẹfa ninu mọlẹbi kan naa

Florence Babaṣọla

 

 

 

Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, Wale Ọlọkọde, ti sọ pe ko si ootọ ninu ahesọ kan to n lọ kaakiri pe wahala awọn agbẹ pẹlu awọn Fulani darandaran lo yọri si iku eeyan mẹfa niluu Waasinmi, nijọba ibilẹ Irewọle.

Ọjọ kẹrinla, oṣu kẹta, ọdun yii, lawọn agbebọn ya wọ Gaa Fulani to wa niluu naa, ti wọn si pa awọn mẹfa ti wọn jẹ mọlẹbi kan naa.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Yẹmisi Ọpalọla, fi sita lorukọ kọmiṣanna rẹ, lo ti ṣalaye pe lọgan tiṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni awọn ọlọpaa ilu Ikire atawọn oṣiṣẹ alaabo mi-in ti lọ sibẹ, ṣugbọn bi awọn agbebọn ọhun ṣe foju kan wọn ni awọn agbofinro ni wọn fẹsẹ fẹ ẹ.

O ni ileeṣẹ ọlọpaa n ṣiṣẹ takuntakun lọwọ lati tanmọlẹ sidii iṣẹlẹ naa, ko si si ibi ti awọn amookunṣika naa le sa lọ ti ọwọ ko ni i tẹ wọn.

Kọmiṣanna fi kun ọrọ rẹ pe ọrọ naa ko ni i ṣe pẹlu ija ẹlẹyamẹya rara, o si kilọ fun awọn ti wọn n dana irọ naa lati kiyesara nitori ko si idagbasoke kankan to le waye nibi ti aibalẹ aya ti ija ẹlẹyamẹya maa n fa ba ti wa.

Bakan naa ni Igbakeji gomina ipinlẹ Ọṣun, Benedict Alabi, ṣabẹwo sibi iṣẹlẹ naa, to si ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bii eyi to buru pupọ.

Alabi, ẹni ti awọn kọmisanna ba kọwọọrin sọ fun awọn agbofinro pe wọn gbọdọ ṣawari awọn ti wọn wa nidii iṣekupani naa, ki wọn si foju winna ofin.

O tun fi awọn araalu lọkan balẹ pe ko sewu fun ẹmi ati dukia wọn nitori lọsan-an loru lawọn agbofinro yoo maa ṣiṣẹ nibẹ lati ri awọn ọdaran naa mu ati lati dena iru iwa bẹẹ lọjọ iwaju.

 

Leave a Reply