Igbakeji gomina Ọyọ ko yọju sawọn aṣofin ti wọn ranṣẹ pe e

Ọlawale Ajao, Ibadan
Nitori bi wọn ṣe fẹẹ yọ ọ nipo, Igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Rauf Ọlaniyan, kọ lati yọju si ileegbimọ aṣofin nigba ti awọn aṣofin ipinlẹ naa ranṣẹ pe e.
Tẹ o ba gbagbe, lati nnkan bii ọsẹ meji sẹyin ti Ẹnjinnia Ọlaniyan ti fi ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party (PDP), to gbe oun pẹlu ọga ẹ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ti i ṣe gomina ipinlẹ naa wọle sipo gomina ati igbakeji gomina.
Lọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja, lawọn aṣofin kan ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP kọwe ẹsun ta ko Ẹnjinnia Ọlaniyan nileegbimọ naa, awọn igbesẹ ti igbakeji gomina naa gbe lẹnu ọjọ mẹta yii lodi si ofin ati ilana iṣejọba.
Wọn ni awọn fẹẹ gbọ awijare rẹ lori awọn ẹsun naa, ati pe ọjọ meje lawọn fun un lati waa wi tẹnu ẹ niwaju awọn, bi ko ba yọju laarin ọjọ meje naa, yiyọ lawọn yoo yọ ọ danu nipo.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni gbedeke ọjọ meje ọhun pe, ṣugbọn igbakeji gomina ko ranṣẹ sawọn aṣofin debi ti yoo yọju si wọn.
Nigba ti n fidi iroyin yii mulẹ, alaga igbimọ to n ri si eto iroyin nileegbimọ aṣofin, Ọnarebu Kazeem Ọlayẹmi, ṣalaye pe “Igbakeji gomina ko ti i fesi si ẹsun ta a fi kan an. Igbakeji gomina funra rẹ lo le dahun boya oun ti fesi si awọn ẹsun ta a fi kan an tabi bẹẹ kọ, ṣugbọn lọdọ tiwa, a o ti i ri esi kankan gba lati ọdọ rẹ”.

Leave a Reply