Igbakeji ọga ọlọpaa Ẹkun kọkanla bẹrẹ iṣẹ

Florence Babaṣọla

Ẹkun kọkanla ileeṣẹ ọlọpaa (Zone XI), eleyii ti ibujoko rẹ wa niluu Oṣogbo ti ni igbakeji ọga agba (AIG), tuntun bayii.

Orukọ rẹ ni Mukan Joseph Gobum psc (+), oun ni yoo maa ṣakoso ipinlẹ Ọyọ ati Ọṣun.

Ọmọ bibi ijọba ibilẹ Kanke, nipinlẹ Plateau, ni, ọdun 1962 ni wọn si bi i. O kẹkọọ-gboye ninu imọ Itan (History), ni Amadu Bello University, Zaria.

Ọdun 1988 lo darapọ mọ iṣẹ ọlọpaa, o si ti ṣiṣẹ loriṣiiriṣii ẹka ko too di kọmiṣanna ọlọpaa lọdun 2017. Ipinlẹ Rivers lo ti di igbakeji ọga agba patapata fun Ẹkun Kẹjọ niluu Lọkọja.

Leave a Reply