Igbakeji olori ileegbimọ aṣoju-ṣofin ilẹ wa tẹlẹ, Lasun Yusuf, fi ẹgbẹ APC silẹ l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọkan lara awọn to dije ninu idibo abẹle funpo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun, Ọnarebu Lasun Yusuf, ti kọwe fi ẹgbẹ naa silẹ bayii.

Lasun Yusuf lo dupo naa pẹlu Gomina Adegboyega Oyetọla ati Alhaji Moshood Adeoti lọjọ kọkandinlogun, oṣu Keji, ọdun yii, ṣugbọn ti Oyetọla fẹyin awọn mejeeji janlẹ.

O ti figba kan jẹ igbakeji olori ileegbimọ aṣoju-ṣofin apapọ orileede yii lasiko ti Ọnarebu Yakubu Dogara jẹ olori ile.

Ọjọ Ẹti, Furaidee,  ni Lasun mu lẹta rẹ lọ si sẹkiteriati ẹgbẹ oṣelu APC to wa lagbegbe Ogo-Oluwa, niluu Oṣogbo.

Gbogbo igbiyanju Alaroye lati gbọ oju ti awọn adari ẹgbẹ naa fi wo lẹta ifẹgbẹsilẹ yii lo ja si pabo nitori gbogbo wọn ni wọn wa l’Abuja fun ipade gbogbogboo ẹgbẹ wọn, ti wọn si sọ pe awọn ko ti i mọ nnkan to wa ninu lẹta naa.

Leave a Reply