Igbanisiṣẹ fun ikọ Amọtẹkun bẹrẹ l’Ekiti

Oluyinka Ṣoyẹmi, Ado-Ekiti

Ikọ Ekiti State Security Network ti gbogbo eeyan mọ si Amọtẹkun ti bẹrẹ igbanisiṣẹ lonii, Ọjọru, Wẹsidee.

Ikede ọhun waye nipasẹ adari ikọ naa, Ọgagun-fẹyinti Joe Kọmọlafẹ.

Awọn ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mejidinlogun si ọgọta ti wọn si ni, o kere ju, iwe-ẹri ileewe alakọọbẹrẹ, ni wọn lanfaani lati forukọ silẹ fun iṣẹ naa.

Ikanni intanẹẹti www.amotekun.ekitistate.gov.ng  lawọn to ba nifẹẹ si iṣẹ Amọtẹkun yoo ti ṣakọsilẹ nipa ara wọn lọfẹẹ, bẹẹ ni wọn yoo ṣe ẹda fọọmu ti wọn fọwọ si lati ori ikanni naa gẹgẹ bii ẹri.

Ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu yii, ni eto igbanisiṣẹ naa yoo wa sopin.

Leave a Reply