Igbẹjọ Timothy Adegoke: Adedoyin ṣepe fawọn oniroyin ni kootu

Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Iyalẹnu lo jẹ fawọn oniroyin laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, yii, nigba ti Dokita Rahmon Adedoyin bẹrẹ si i ṣepe fun wọn pe wọn n ya fọto oun.

Adedoyin lo ni ileetura Hilton to wa niluu Ileefẹ, nibi ti akẹkọọ Fasiti OAU kan, Timothy Adegoke, ku si loṣu Kọkanla, ọdun to kọja.

Adedoyin ati awọn oṣiṣẹ rẹ mẹfa ni wọn n jẹjọ lori ẹsun bii mọkanla ti wọn fi kan wọn.
Loṣu kan sẹyin to yẹ ki awọn olujẹjọ bẹrẹ awijare wọn niwaju Onidaajọ Adepele Ojo ti ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ọṣun ni agbẹjọro fun Adedoyin, Barisita Ẹlẹja (SAN), sọ pe ko ni ẹlẹrii kankan lati pe.

Nigba to yẹ ki awọn olujẹjọ yooku bẹrẹ awijare ni ọkan lara wọn, Magdalene, bẹrẹ aisan ninu kootu, lẹyin-ọ-rẹyin ni wọn sun igbẹjọ di oni.

Nnkan bii aago mẹsan-n kọja iṣẹju mẹwaa aarọ Ọjọruu ni wọn ko awọn mejeeje de sinu ọgba ile-ẹjọ, nigba ti wọn si n to wọn lọwọọwọ wọnu kootu ni Adedoyin duro lojiji, o kọju si awọn oniroyin, o ni ‘Afi to ba jẹ pe loootọ ni mo pa Timothy Adegoke ni ẹyin ti ẹ n ya fọto yii ko fi ni i jiya laye’.

Ni bayii, igbẹjọ ti bẹrẹ ni pẹrẹu.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//lephaush.net/4/4998019
%d bloggers like this: