Igbẹkẹle to mura bii obinrin atawọn ẹmẹwa rẹ ya wọ ṣọọsi l’Akurẹ, ni wọn ba ji eeyan mẹrin gbe

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọwọ ẹsọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo ti tẹ ọkan ninu awọn ajinigbe to ya wọ inu sọọsi kan l’Akurẹ, ti wọn si ji awọn obinrin mẹrin gbe sa wọgbo lọ.

Afurasi tọwọ tẹ ọhun, Igbẹkẹle, ni wọn lo dibọn, to si mura bii obinrin lasiko tawọn ẹṣọ Amọtẹkun lọọ ka wọn mọ ibi ti wọn fi ṣe ibuba ninu igbo kan nitosi Ado-Ekiti.

Nigba ti wọn n ṣafihan awọn afurasi ọhun lolu ileeṣẹ wọn to wa ni Alagbaka, lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee, Alakooṣo ẹṣọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ, ni ẹnikan to raaye jajabọ mọ awọn ajinigbe naa lọwọ lo pe awọn sori ago.

O ni aarin wakati kan pere ti wọn ji awọn eeyan ọhun gbe lawọn kan wọn lara ninu igbo ti wọn ko wọn lọ.

O fi kun un pe iya arugbo ẹni ọdun mejidinlọgọrin kan wa ninu wọn, ti ẹni to dagba tẹle e si to bii ẹni ọdun marundinlaaadọta nigba tawọn meji yooku jẹ ọlọmọge, ọkan ninu awọn ọlọmọge naa lo ni o jẹ akẹkọọ kọlẹẹji eto ilera kan to wa ni Ijero-Ekiti.

Gbogbo aṣọ ara awọn obinrin yii lo ni wọn gba, ti wọn si ti ṣe wọn niṣekuṣe ninu igbo kawọn ẹṣọ Amọtẹkun too de.

 

Lara awọn aṣọ alasọ ti awọn ajinigbe naa n gba lara awọn to ba ti wa ni igbekun wọn lo ni Igbẹkẹle n wọ, ti yoo si ko omiiran saya lati fi tan awọn eeyan jẹ pe obinrin loun

O ni ṣe ni wọn gba ọmọ osu marun-un ti ọkan ninu awọn ti wọn ji gbe ọhun gbe pọn lẹyin rẹ laimọ ohun ti wọn fẹẹ fi ọmọdekunrin naa ṣe.

Oloye Adelẹyẹ ni iwadii awọn ṣi n tẹsiwaju lori bọwọ yoo ṣe tẹ awọn ikọ ajinigbe yooku to sa mọ awọn lọwọ.

Gbogbo awọn ti wọn ko ni igbekun ọhun lo ni awọn kọkọ ko lọ sile-iwosan lati gba itọju to peye ni kete ti wọn ri wọn ko pada siluu Akurẹ. Ọkunrin naa ni meji ninu wọn ṣi n gba itọju lọwọ latari ohun ti wọn foju wina latọwọ awọn janduku to ji wọn gbe.

Yatọ si ikọ ajinigbe tọwọ tẹ yii, awọn afurasi mọkanlelogun mi-in lo ni wọn tun ti wa lakata awọn lori ọkan-o-jọkan ẹsun bii idigunjale pẹlu ẹsun jibiti ori ẹrọ ayelujara.

O ni awọn afurasi bii marundinlọgọrin ni wọn ti ko si panpẹ awọn laarin ọsẹ meji pere ti awọn bẹrẹ eto kan ti wọn n pe ni gbaluu-mọ (Operation Clean Up).

Pupọ awọn afurasi ọdaran tọwọ tẹ naa lo ni awọn ti ko lọ sile-ẹjọ, nigba ti iwadii n lọ lọwọ lori ọkan-o-jọkan ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Leave a Reply