Igbesẹ tijọba Kwara gbe lati gbogun ti magomago lasiko idanwo jẹ iwuri fun wa – WAEC

Stephen Ajagbe

Ajọ to n mojuto idanwo aṣekagba, WAEC, ti lu ijọba Kwara lọgọ ẹnu fun igbesẹ to gbe lati dẹkun magomago lasiko idanwo.

Adari ẹka to n mojuto idanwo naa Ọgbẹni Adesọji Fabọrọ, sọrọ ọhun nibi ipade igbimọ to n mojuto idanwo WAEC ọdun 2020 to waye ni olu ileeṣẹ ajọ WAEC.

Fabọrọ ni, bijọba ṣe gbe awọn ọga agba ileewe kaakiri lasiko idanwo naa, ti wọn si tun lo awọn olukọ ileewe giga lati mojuto eto idanwo naa jẹ eyi to dara.

O ni yoo mu ki ṣiṣe magomago ninu idanwo dinku, yoo si mu idagbasoke ba eto ẹkọ nipinlẹ Kwara.

O gba kọmiṣanna feto ẹkọ niyanju lati jẹ ki igbesẹ tijọba gbe naa tẹsiwaju.

Ipinlẹ Kwara wa lara awọn ti ajọ WAEC paṣẹ fun laipẹ yii lati san owo itanran fun ṣiṣe magomago idanwo.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Tori pe wọn yinbọn paayan meji, afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun meje dero ahamọ l’Abẹokuta

Gbenga Amos, Abẹokuta Lati ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Karun-un yii, lawọn gende mẹrin …

Leave a Reply

//unbeedrillom.com/4/4998019
%d bloggers like this: