Igbeyawo Akin: Ṣe aye mi daa tabi ko daa

A ti lọọ tọrọ iyawo Akin. N ko le sọ pe o dun mi tabi ko dun mi, nitori inawo naa ko lọ bi mo ṣe fẹ. Niṣe ni pasitọ to jẹ baba iyawo wa n ṣe bii ẹni pe nnkan eewo ni ọmọ oun ṣe, to ṣaa n ṣe balubalu kiri bii ẹyẹle Subaina. Iyawo ẹ lo pero, tipatipa lo fi mu awọn mẹta ti wọn ni ẹbi ẹ  ni wa. Ṣugbọn sibẹ naa, awọn ẹbi iyawo ẹ ṣe bẹbẹ, nigba to si fẹẹ maa ṣe iranu, wọn gba yẹyẹ si ẹgbẹ kan, a yaa n ṣe nnkan wa lọ. Emi o kuku tiẹ wo oju ẹ, nitori gbogbo ohun to ti ba jẹ mọ iranu bẹẹ yẹn, paapaa lori ọrọ ẹsin, ko ba emi nile, mo koriira rẹdẹrẹdẹ.

Ṣugbọn ọkan ninu ohun to dun mọ mi ninu ju ni idunnu ti mo ri loju Akin ati iyawo ẹ yii. Wọn ma fẹran ara wọn o. Ani Akin ni bo ba jẹ ẹni kan ni wọn pe, ka ṣaa ti lọọ ṣe e. Mo ni ti wọn ba waa pe ẹni kan pere, ta lo fẹẹ mu lọ. O ni ta lo loun fẹẹ mu lọ, baba oun ni, oun ko le mu ẹlomi-in lọ. Mo ni iyẹn ni pe to ba jẹ ẹni kan ni wọn ni ko mu wa nile ana ẹ, ko ni i mu mi lọ. Lo ba n rẹrin-in, lo ba loun ko le mu mi lọ, baba oun loun maa mu lọ sibẹ. Mo ni kin ni idi, o ni ko si idi kankan, baba oun loun kan maa mu lọ naa ni.

Ṣe ẹ ri awọn ọmọ yii! Ọmọ ti emi n tori ẹ ku lọ! Baba ẹ lo mọ, ko mọ emi! Niṣe lo da bii ki n pa awọn itan iwa buruku kan fun un ti iba jẹ ko mọ iru eeyan ti baba ẹ jẹ. Ṣugbọn mo sinmi, ọbẹ ki i mi nikun agba. Iro tiẹ si ni, ṣe o fẹẹ sọ pe oun ko mọ ohun ti baba ẹ foju mi ri lasiko ileewe ẹ, to jẹ ọwọ mi lo ti maa gba gbogbo owo, titi de ori owo mọto to kere ju lọ. Akin mọ, o mọ daadaa, o kan jẹ Ọlọrun lo mọ ibi ti oun ati baba ẹ di i si ni. O mọ gbogbo wahala ti mo sẹ, ṣugbọn ko jẹ tori ẹ binu si baba ẹ, emi ni alariifin ẹ. Kẹ ẹ maa wo ile aye o.

Eyi to tiẹ ya mi lẹnu ni ti Biọla to n sunkun lori foonu, to ni oun fẹẹ wa sile. Ṣugbọn nigba ti mo sọ fun un pe ko ma dan an wo, pe ọsẹ meji ni wọn yoo fi karantain ẹ n’Ikẹja, oun naa ni ọsẹ meji ni wọn yoo fi karantain oun ti oun ba tun de, mo ni ko yaa jokoo ẹ jẹẹ. Ohun to n pa a nigbe niyẹn. O ni ki Akin fi fọto Tinukẹ, iyẹn iyawo ẹ, ranṣẹ soun. Lawọn naa ba sare lọọ ya fọto, oriṣiiriṣii fọto ni wọn ya, ti Akin ba buruburu mọ iyawo ẹ lẹgbẹẹ. Ohun to si n ya mi lẹnu ju niyẹn, nitori bi wọn ba ni Akin yoo maa tẹle obinrin kan bayii, n oo sọ pe irọ ni.

Tinukẹ naa n kọ, nibi ti a ti n ṣeto gbogbo, bo ba wo oju Akin bayii, yoo ṣaa maa rẹrin-in ni. Bẹẹ ni yoo waa jokoo le mi lẹsẹ ti yoo maa fọwọ pa mi lara bii ologbo. Mo ro o sinu ara mi pe to ba jẹ bi ọmọ yii ṣe ri delẹdelẹ niyi, a jẹ pe Ọlọrun lo fi iwa mi kẹ mi. Emi naa ki i sẹ eeyan buruku, n ko ni iya ọkọ kan tabi aburo ọkọ kan, tabi ẹgbọn ọkọ kan lara ri, gbogbo ohun ti mo ba si fẹẹ ṣe fun wọn, pẹlu ifẹ ati itẹriba ni. Bi Akin naa ba waa fẹ ọmọ to ni iwa, to si ni ẹkọ ile daadaa bayii, a jẹ pe Ọlọrun lo fi iwa mi kẹ mi.

Alaaji ti ni gbogbo nnkan loun gba, awọn alaafaa yoo so yigi iyawo ọmọ oun. Ọtọ la kọkọ fa iyẹn. N la ba fi adura ibẹrẹ si aago mejila lọsan-an. Aṣe Akin ti ba awọn kan di bageeni kan ti awa ko mọ. Sẹki lo sọ fun mi, to ba si jẹ mo fẹẹ ba gbogbo ẹ jẹ ni, ti n ba sọ fun baba ẹ, ko ni i jẹ ka ṣe e. Lemi naa ba yaa sinmi. Baba Tinukẹ, pasito jakujaku yẹn ti ko awọn pasitọ ẹgbẹ ẹ lẹyin, wọn si sare ṣe adura igbeyawo fun Akin ati Tinukẹ ni aago mẹjọ si mẹwaa aarọ. Ti wọn n kọrin ṣọọṣi wọn ni rẹpẹtẹ. Sẹki ati ọkọ ẹ ni wọn lọọ duro bii baba ati iya iyawo.

Ki awa too debẹ ni aago mejila, wọn ti pari gbogbo iyẹn, koda eeyan ko le mọ pe wọn ti sẹ nnkan kan nibẹ, awọn to n dana nikan lawa ri. Mo ṣẹṣe waa mọ idi ti ara pasitọ ko fi balẹ nigba ti awa debẹ ni, bo ti n lọ lo n bọ, ti ko jokoo si oju kan. Awọn aafaa ko kuku wo oju ẹ, awọn yaa n dana hutubaa le awọn ọmọ lori ni tiwọn, ti wọn si n da waka. Bi a ṣe n nawo fun wọn to ni waka n pọ si i, awọn naa si gba kinni kan, pirigidi owo ni. Nigba ti wọn tun so yigi tan naa n kọ, awọn Seki ati Safu pa itu meje, awọn atawọn ọrẹ wọn.

N o tiẹ royin fun yin. Awa ti a ni a ko ni i ju mẹwaa lọ, a le logun daadaa. Alaaji Agba wa, wọn ni afi bawọn ba ku nikan lawọn ko ni i debẹ, Baba Lemọmu, iyẹn Baba Safu wa, Safu ni ko sohun ti oun le ṣe si i, bi aburo oun ba n gbeyawo, baba oun gbọdọ wa nibẹ. Lati Ageege nikan, awọn bii mẹjọ ni wọn wa. Awọn ọrẹ Sẹki bii meje lo wa nibẹ, ohun to jẹ ki awọn alaafaa ri owo gba niyẹn. Em ti mo si ti sọ pe n o fẹ ariwo, ẹnu ya mi nigba ti mo pada de ti mo ba awọn ọrẹ Alaaji, ati awọn ọrẹ Sẹki ati awọn ọmọ ẹgbẹ mi. Ani mo ba wọn ti wọn n kun maaluu, odidi maaluu kan.

Ta lo waa n na gbogbo owo yii, nitori ko ma si ẹni kan to beere kọbọ lọwọ mi. Aṣe Sẹki ati Safu ni. Awọn mejeeji. Awọn ni wọn pe gbogbo ero to wa nibẹ, awọn ni wọn dana, bẹẹ ohun ti mo sọ fun wọn ni pe ki wọn lọọ yọwo awọn ohun ti wọn ba fẹẹ ra fun iwọnba awọn eeyan bii ọgbọn, ki wọn si fun awọn araale lounjẹ. Ni wọn ba ni ti awọn ba ṣetan, awọn aa sọ iye ti awọn ba na fun mi. Mo ṣaa ri i ti wọn n se ti wọn n sọ, mo ri ero ti wọn n jẹun, awọn ọrẹ Alaaji tun muti yo, mo mọ pe inawo naa kọja ohun ti mo ro. Njẹ ki n beere iye ti wọn na, wọn ni ko si eyi to kan mi nibẹ, awọn lawọn n ṣeyawo aburo awọn. Haa, ni mo n ṣe. Aye mi dara tabi ko daa!

Ẹ ẹ mọ eyi to dun mọ mi ninu ju ninu gbogbo ohun to ṣẹlẹ yii. Awọn eeyan mẹta kan wọ aṣọ kan naa, awọn mẹtẹẹta yoo si ya yin lẹnu. Iyaale wa agba, Akin ati Tinukẹ iyawo ẹ. Loootọ ni mo ni ki Akin waa sọ iru aṣọ ti wọn ba fẹẹ wọ fun mi ki n le ra a fun wọn, ṣugbọn o ni ki n ma ṣeyọnu, awọn ti ra a. Aṣe iyaale wa agba, Iyaa mi, Iyaa Sẹki, ni wọn ti sọ pe ẹni kẹni ko ni i ra aṣọ fun ọmọ awọn ati iyawo ẹ. Sẹki bura fun mi pe oun ko fun iya lowo kankan, oun ko si mọ, nitori wọn sọ fun Akin pe ko gbọdọ sọ fẹnikan. Iya mi ti ko lowo, ti ko ṣiṣẹ, oun lo ra aṣọ ti Akin ati iyawo ẹ wọ, ati eyi ti awọn naa wọ. Niṣe ni gbogbo wa ṣi ẹnu kalẹ ti a n woran!

Leave a Reply