Igbeyawo Flakky Ididowo daru patapata, ile-ẹjọ ni ki wọn lọọ ṣayẹwo ẹjẹ lati mọ ẹni to lọmọ

Faith Adebọla

Afi bii owe akisa to n lọ si akitan, ti ki i gbọ riran, to jẹ pe bi wọn ba ran an loke, niṣe ni yoo ya nisalẹ, bẹẹ lọrọ ri nipa igbeyawo ọkan lara awọn ilu-mọ-ọn-ka oṣere-binrin ilẹ wa nni, Ronkẹ Odusanya, tawọn eeyan mọ si Flakky Ididowo, pẹlu ọkọ ẹ, Ọlanrewaju Saheed, ti inagijẹ rẹ n jẹ Jago. Niṣe lọrọ wọn tubọ n sun mọ ikorita ipinya, ẹkọ ko si ṣoju mimu fun wọn rara lasiko yii.

Tuntun to ṣẹṣẹ ṣẹlẹ nipa wọn ni bi ile-ẹjọ Majisreeti to wa ni kootu kẹjọ, Samuel Ilọri Court House, ni Ọgba, nipinlẹ Eko, ṣe paṣẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii, pe afi kawọn onimọ iṣegun ba tọkọ-taya naa fi imọ ẹrọ yẹ ẹ wo lati mọ ẹni to jẹ baba ọmọbinrin ti wọn lawọn bi ọhun, Oluwafifẹhanmi.

Jago lo sọ nile-ẹjọ nigba ti igbẹjọ n lọ lori ọrọ wọn pe koun too le sọrọ lori itọju ati gbigbọ bukaata lori ọmọ naa, afi koun kọkọ ri aridaju pe ọmọ oun lọmọbinrin naa loootọ, o loun fẹ kile-ẹjọ faṣẹ si i lati lọọ ṣe ayẹwo tawọn eleebo n pe ni DNA (Deoxyribonucleic Acid), fun un.

Kẹmika DNA yii lo maa n ṣe ifọsiwẹwẹ awọn eroja to wa lara ọmọ ati ti obi, o si maa n fi iyatọ ati ijọra han laarin obi ati ọmọ, debii pe kedere lo maa han to ba jẹ eroja iya ati baba papọ pẹlu tọmọ ti wọn n jiyan le lori. Bi ko ba si papọ, afi kiyaa ọmọ naa tete ṣalaye ibi to ti royun he, ko si jẹwọ baba ọmọ gan-an.

Lọpọ igba, bi ariyanjiyan ba waye lori ẹni to jẹ baba ọmọ gan-an, tabi ti baba ọmọ ba n fura pe afaimọ ni ko ma jẹ ọmọ ale niyawo oun pe lọmọ oun, ni ibeere fun iru ayẹwo akanṣe yii maa n waye.

Iru ayẹwo yii ki ṣe ọrọ inawo kekere rara, tori ẹ, niṣe ni Ronkẹ ati lọọya rẹ beere pe ta lo fẹẹ sanwo ayẹwo ọhun, ile-ẹjọ si paṣẹ pe Ọgbẹni Saheed to beere fun un ni ko bojuto inawo to ba tidi ẹ yọ.

Ronkẹ tun rọ ile-ẹjọ lati paṣẹ pe ọsibitu ti awọn agbofinro ti maa raaye mojuto bi nnkan ba ṣe n lọ ni ki wọn ti ṣe ayẹwo naa, o ni ibi ti ko ti ni i saaye fun magomago kan ninu eto ayẹwo naa lo maa daa, ile-ẹjọ si fọwọ si i bẹẹ, wọn ni kootu naa maa mojuto bi nnkan ba ṣe lọ si.

Adajọ-binrin M. O. Tanimọla paṣẹ pe ki wọn lọọ ṣayewo DNA ọmọ wọn ọhun ni ọsibitu kan ti wọn forukọ bo laṣiiri ni Lagos Island, lọsibitu naa wa, ati pe taarata ni ileewosan naa maa fi abajade esi ayẹwo wọn ranṣẹ si ile-ẹjọ, ko maa baa si aaye fẹnikẹni lati ṣe magomago si esi naa.

Ṣe o waa le jẹ pe Jago kọ ni baba ọmọbinrin wọn yii loootọ? Ibeere yii lawọn ololufẹ Ronkẹ n beere, wọn lo maa ya awọn lẹnu tọrọ ba lọọ bẹyin yọ, bẹẹ si lawọn kan n sọ pe ki wọn mu suuru de esi ayẹwo na, ayẹwo lo maa fidi okodoro otitọ mulẹ.

Ṣe o ti to ọjọ mẹta kan ti nnkan ti daru laarin arẹwa oṣẹre-binrin yii pẹlu ọkọ ẹ. Obinrin naa lo kọkọ fẹsun kan baba ọmọ rẹ pe ko ba oun gbọ bukaata lori ọmọ, fain bọi lo n ṣe kiri igboro, o lo n yan ale, ko si huwa bii ọkọ gidi soun. Ka too wi, ka too fọ, obinrin naa ti pe ọkọ rẹ lẹjọ sile-ẹjọ to n gbọ ẹsun akanṣe ati iwa ọdaran abẹle, lagbegbe Ikẹja.

Jago naa ko gbe ẹnu ẹ falagbafọ o, oun naa rojọ nipa iyawo ẹ, o ni obinrin naa n ṣe ṣina, oun o si le fọkan tan an mọ.

Awọn ololufẹ wọn ti sapa lati da sọrọ ipinya awọn mejeeji yii, bi wọn ṣe n ba ọkọọkan wọn sọrọ lojukoroju ni wọn n fi ọrọ ranṣẹ si wọn lori awọn ikanni ajọlo tawọn mejeeji wa, ṣugbọn nibi tọrọ de yii, o jọ pe irawe igbeyawo wọn yii ti dajọ ilẹ, ko tun le duro soke mọ, tọkọ-taya naa fẹẹ pin gaari ni poo.

Leave a Reply