Monisọla Saka
Gbajugbaja arẹwa oṣerebinrin onitiata nni, Toyin Abraham ati ọkọ ẹ toun naa jẹ onitiata, Kọlawọle Ajeyẹmi, ti ni irọ to jinna si ootọ ni pe wahala n ṣẹlẹ ninu ile awọn, ati pe niṣe ni ọkọ Toyin, Kọla n rọju ninu igbeyawo naa.
L’Ọjọbọ Tọsidee, ọsẹ yii, ni akọroyin ori ẹrọ ayelujara kan gbe e pe wahala ti wa ninu ile Toyin Abraham naa, bi ko ba si ṣọra, afaimọ ki igbeyawo oun ati oṣere ẹgbẹ rẹ yii ma tu ka. O ni ẹnikan ti ọkọ Toyin fọrọ aṣiri si lọwọ nipa ohun to n lọ nile wọn ati bi ohun gbogbo ṣe su u lo tu aṣiri naa pe aarin tọkọ-taya naa ko fi bẹẹ gun.
O sọ pe ọkọ Toyin fẹsun kan an pe bo ṣe wu u lo maa n jade nile ti ko ni i dagbere, o ni o le lo ọjọ mẹrin tabi ju bẹẹ lọ ti ko ni i wale, ti ko si ni i ṣe ojuṣe rẹ gẹgẹ bii iyawo si awọn ọmọ.
Ẹni to gbe iroyin naa jade sọ pe gbogbo awọn ọrọ ifẹ ti Toyin maa n gbe jade lori ikanni rẹ nigba mi-in, o maa fi n dọgbọn bẹ ọkọ rẹ ni. Bẹẹ lo ni ki i tẹle wọn lọ si ṣọọṣi lọjọ isinmi mọ.
Gẹgẹ bi oniroyin naa ṣe sọ, o ni ọrọ Toyin ti su ọkọ ẹ, koda ko too di pe o loyun ni ina ọrọ naa ti n ru, ṣugbọn ti Kọla n fọgbọn ṣe e ki ile wọn ma baa daru. Lile ti ọrọ naa n le si i, ti ko si mọ ọna to le gbe e gba lo jẹ ko bẹ ọrọ naa sita. Loootọ, ki i ṣe Kọlawọle Ajeyẹmi funra ẹ lo sọrọ yii sita, ohun ti iroyin sọ ni pe, ọrẹ ti Kọla fọrọ lọ nigba ti ọrọ naa le ju ẹmi ẹ lọ lo gbe ọrọ naa sita.
Ṣugbọn Toyin ati ọkọ rẹ ti sọ pe irọ to jinna si ootọ ni ahesọ ti oniroyin ori ayelujara yii n gbe kiri, o ni igbeyawo awọn ko mi rara, bẹẹ ni ko si ede aiyede kankan laarin awọn.
Yatọ si fidio kan to gbe sori Instagraamu rẹ, eyi to ṣafihan tọkọ-taya naa ati ọmọ ti Kọlawọle ti kọkọ bi fun obinrin mi-in ti wọn jọ n jo ninu fidio ọhun, agbẹnusọ Toyin lori eto iroyin tun fi atẹjade sita, nibi to ti sọ pe ki awọn eeyan ma ka ọrọ ahesọ to n jade naa si.
Ninu atẹjade ti wọn fi lede ọhun lo ti ni, “Laipẹ yii la ri irọ nla ati iregbe kan tawọn eeyan n sọ nipa oṣerebinrin wa, Toyin Abraham ati ọkọ ẹ toun naa jẹ irawọ oṣere, iyẹn, Kọla Ajeyẹmi. Lọpọ igba, awọn eeyan maa n ni ti ko ba nidii, obinrin ki i jẹ kumolu, ti ko ba si ina, a ko le ri eefi, ṣugbọn lakooko yii o, a n fi ọkan awọn ololufẹ Toyin ati Kọla Ajeyẹmi balẹ pe ko si eefi depodepo ina.
Ko si ootọ kan ninu ọrọ naa, irọ nla to jinna si ootọ ni. Toyin o figba kankan sun ita, ayafi to ba wa ni oko ere tabi to rinrin ajo kuro ninu ilu nitori iṣẹ ẹ.
Koda lọpọlọpọ igba, oun atọkọ ẹ ni wọn dijọ maa n lo isinmi nilẹ yii ati loke okun”.
Ṣe ko pẹ pupọ ti iroyin jade pe igbeyawo Funkẹ Akindele toun naa jẹ oṣere ati ọkọ rẹ ti daru. Lẹyin eyi ni wọn n gbe e kiri pe igbeyawo Toyin naa ti n mi lẹsẹ, ṣugbọn oṣere yii ati ọkọ rẹ ti sọ pe ko si ootọ ninu rẹ. Bẹẹ lawọn alatilẹyin wọn ti n gbadura kikan kikan fun wọn pe ko si ohun to maa ṣe igbeyawo naa, wọn maa bara wọn dọjọ alẹ ni.