Igbeyawo Zainab daru n’Ibadan, aisan ibalopọ lo da wahala silẹ

Aderounmu Kazeem

Ile-ẹjọ kan ni Mapo, niluu Ibadan, ni igbeyawọ ọdun mọkanla kan ti daru, nibi ti Nurudeen Mabinuori ati Zainab ti kọ ara wọn silẹ patapata.

Ẹsun ti ọkọ fi kan iyawo ni pe niṣe lobinrin naa n fi ibasun jẹ oun niya. Bẹẹ ni Zainab naa sọ pe ọkọ oun ti ko arun ibalopọ, oun ko si le jẹ ko fi tiẹ ko ba oun.

Oloye Henry Agbaje, ẹni ti ṣe Aarẹ ile-ẹjọ naa sọ pe gbogbo ipa to yẹ ni ile-ẹjọ naa ti sa lati yanju wahala to wa laarin awọn tọkọ-tiyawo naa, ṣugbọn niṣe ni wọn yari, ti wọn si sọ pe ki ile-ẹjọ da igbeyawo ọdun mọkanla to wa laarin awọn ru.

ALAROYE gbọ pe nigba ti ọrọ naa ko lojutuu mọ gan-an lo mu Aarẹ Agbaje tu wọn ka, to si pa Mabinuori laṣẹ ko maa san ẹgbẹrun marun-un naira fun iyawo ẹ loṣooṣu gẹgẹ bi owo ounjẹ fun ọmọ ti obinrin naa bi fun un.

Bakan naa lo tun pa Mabinuori laṣẹ ko san owo ile ti obinrin naa n gbe, ti iye ẹ jẹ ẹgbẹrun mẹrinlelọgọrin naira (N84,000).

Ọkọ yii ti sọ pe ko ni i wu oun lati maa ba obinrin naa gbe mọ nitori alagidi kan bayii ni, ati pe niṣe lo maa n fi iya ibasun jẹ oun gidgidi.

Zainab ni tiẹ sọ pe niṣe lọkunrin naa ko sọ ootọ ọrọ to wa nibẹ rara. O ni oniṣina ni ọkọ oun, ati pe nibi to ti n ba oriṣiriiṣi obinrin sun kiri lo ti ko aisan, bẹẹ lo kọ lati lọọ gba itọju lọsibitu. O ni idi pataki ti oun ko fi gba a laaye ki o maa ba oun sun mọ niyẹn.

Obinrin yii tun fi kun ọrọ ẹ pe awọn obi ọkọ oun paapaa mọ si ohun to n fa wahala laarin awọn, bẹẹ lo sọ ọ niwaju Aarẹ ile-ẹjọ ọhun wi pe ọrọ okunrin naa ti su oun, ki wọn tu awọn ka, ki kaluku maa ba tiẹ lọ.

 

Leave a Reply