Igbimọ alaṣẹ Fasiti Ibadan ko lagbara lati fiya jẹ wa- Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Nitori bi igbimọ alaṣẹ to ga ju lọ ni Fasiti Ibadan (UI), ṣe pinnu lati fiya jẹ awọn oṣiṣẹ fasiti naa to ta ko ọna ti wọn gba ṣeto lati yan oludari agba UI tuntun, ẹgbẹ awọn agba oṣiṣẹ Fasiti Ibadan ta a mọ si Senior Staff Association (SSANU), ati ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ti ki i ṣe olukọni ni fasiti naa, iyẹn Non Academic Staff Union (NASU), ti sọ pe igbimọ naa ko to bẹẹ lati fiya jẹ awọn.

Nibi ipade oniroyin kan to waye nile ẹgbẹ SSANU ninu ọgba Fasiti Ibadan, ni wọn ti sọrọ naa l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja, lawọn ọmọ ẹgbẹ SSANU ati NASU ṣe iwọde ta ko ọna ti awọn alaṣẹ UI  gba ṣeto lati yan oludari agba tuntun fun fasiti naa.

Eyi lo mu ki igbimọ to ga ju lọ ti wọn n pe ni Senate kede ninu ipade wọn l’Ọjọruu, Wẹsidee ana, pe awọn yoo fiya nla jẹ wọn nitori wọn huwa ikọja aaye ati afojudi.

Ṣugbọn ti awọn alaṣẹ ẹgbẹ naa sọ ninu ipade oniroyin ti awọn paapaa ṣe l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, pe wọn ko to bẹẹ lati fiya jẹ awọn.

Gẹgẹ bi Ọgbẹni Wale Akinrẹmi ti i ṣe alaga ẹgbẹ SSANU ni fasiti naa ṣe sọ, “Loootọ lawa ta a jẹ oṣiṣẹ ti ki i ṣe olukọ ni fasiti yii ko ni ipa kankan lati ko ninu ọna ti wọn maa n gba yan VC (oludari agba fasiti) ṣugbọn ta a ba ri i pe ọna ti wọn gbe eto yẹn gba ko daa, a ni lati pe wọn sakiesi, nitori ti wọn ba gbe e gba ọna ti ko daa, o le di ohun ti wọn yoo tori ẹ gbe ara wọn lọ sile-ẹjọ, itiju gbogbo wa lo si maa jẹ.

 

Leave a Reply