Igbimọ agba ẹgbẹ APC Eko fontẹ lu saa keji Sanwo-Olu

Faith Adebọla, Eko
Bi Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, ba bẹrẹ mọlẹ to mujo jo lasiko yii, o to bẹẹ, tori ẹkọ ti n ṣoju mimu bọ fun ọkunrin naa, igbimọ to n fun gomina lamọran nipinlẹ Eko, Governor’s Advisory Council (GAC), ti fọwọ si i pe ki gomina naa lọ fun saa keji lori aleefa.
Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹrin yii, ni igbimọ awọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, ti ipinlẹ naa ṣepade nile ijọba Eko to wa lagbegbe Marina.
Bo tilẹ jẹ pe ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni eto idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu naa lati yan ondije funpo gomina yoo waye, o ti foju han bayii pe Sanwo-Olu lẹgbẹ naa yoo fa kalẹ, o si ṣee ṣe ko ma si alatako mi-in ninu ẹgbẹ wọn.
Ọ jọ pe ipinnu awọn agbaagba ẹgbẹ yii ni Sanwo-Olu n duro de, bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to ti i gba fọọmu sipo gomina ninu ẹgbẹ naa.
Tẹ o ba gbagbe, igbimọ awọn agbaagba yii wa lara ohun to ṣẹ gomina ana, Akinwunmi Ambọde, lẹyin, latari bi wọn ṣe kọ lati fọwọ si saa keji fun un lasiko ti ijọba rẹ tẹnu bepo lọdun 2019.

Leave a Reply