Igbimọ alamoojuto PDP: Jubrin lọ, Wabara wọle

Faith Adebọla

 Lọna lati wa ojutuu si fa-a-ka-ja-a to ti n waye ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, paapaa laarin Gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike, ati oludije funpo aarẹ wọn, Atiku Abubakar, atawọn alatiyẹn wọn, Alaga igbimọ alamoojuto ẹgbẹ naa, (Board of trustee) Alaaji Walid Jibrin, ti kọwe fipo silẹ, pe oun yọnda ipo oun gẹgẹ bii alaga igbimọ awọn agbaagba ẹgbẹ, wọn si ti yan Adolphos Wabara, olori awọn aṣofin Naijiria nigba kan, lati rọpo rẹ gẹgẹ bii Adele.

Bakan naa ni wọn tun yan an lati jẹ oludamọran pataki fun Alaga apapọ ẹgbẹ naa, Iyorchia Ayu.

Igbesẹ yii waye nibi ipade akanṣe ti igbimọ amuṣẹṣe ẹgbẹ naa ṣe l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹsan-an ta a wa yii, lolu-ile ẹgbẹ wọn to wa l’Abuja.

Idi pataki ti wọn fi pe ipade naa da lori awuyewuye ati itahun-sira-ẹni to ti n lọ laarin Wike, Ayu ati Atiku, pẹlu awọn alatilẹyin wọn, ki wọn le wa ọna lati bomi pana rẹ ki ija naa too fẹju.

Ba a ṣe gbọ, wọn ni Atiku Abubakar ti damọran pe ki Ayu naa kọwe fipo silẹ lati le jẹ ki ẹlomi-in lati iha Guusu orileede yii bọ sipo alaga ẹgbẹ, ki awọn tinu n bi si le fẹdọ leri oronro. Ṣugbọn wọn lawọn alenulọrọ kan duro lẹyin alaga ọhun, wọn o fẹ ko kuro nipo lasiko yii.

Bakan naa ni ẹnikan to wa nibi ipade naa sọ pe o ṣee ṣe ki Alaga ẹgbẹ awọn gomina PDP, Aminu Tambuwal, kọwe fipo silẹ gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ naa.

Ṣibaṣiba lẹsẹ awọn gomina, aṣofin apapọ, atawọn ijoye ẹgbẹ, titi kan awọn alẹnulọrọ ẹgbẹ oṣelu PDP pe sibi ipade akanṣe ọhun, ipade naa ṣi n tẹsiwaju lasiko ta a fi n ko iroyin yii jọ.

Leave a Reply