Monisọla Saka
Igbimọ to n ri si eto ipolongo ibo aarẹ Bọla Tinubu ti sọrọ lori ohun ti wọn ni oludije dupo aarẹ naa sọ gẹgẹ bii aṣigbọ latọdọ awọn oniroyin, ati wi pe ko sọ ọrọ naa lati fi yẹyẹ Aarẹ Muhammadu Buhari.
Tẹ o ba gbagbe, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja yii, lakooko ti Tinubu ṣabẹwo si awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ogun lo sọ bi o ṣe gbe Aarẹ Buhari, Gomina Dapọ Abiọdun tipinlẹ Ogun atawọn mi-in depo ninu oṣelu.
Ninu atẹjade kan ti adari eto iroyin eto ipolongo Tinubu, Bayọ Ọnanuga, fọwọ si lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii lo ti ni wọn ṣapejuwe ọrọ ti Tinubu sọ gẹgẹ bii eyi ti ko daa rara, ọrọ to le, eyi to kun fun awọn aleebu kan.
Ọnanuga ṣalaye pe ọrọ ita gbangba, to si tun jẹ ootọ pọnnbele ti wọn ti n yiri ẹ wo latọdun to ti pẹ ni Tinubu sọ.
Ninu atẹjade ọhun lo ti ni, “Wọn ti pe akiyesi awọn igbimọ to wa fun ipolongo eto idibo Tinubu si itukutuu ti wọn tu ọrọ ti Aṣiwaju sọ l’Abẹokuta, ipinlẹ Ogun l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.
“O wa lakọsilẹ pe ẹni to ṣi n le waju lọwọ ninu awọn oludije dupo aarẹ lẹgbẹ APC, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ba awọn aṣoju apapọ ẹgbẹ oṣelu naa sọrọ nipinlẹ Ogun, gẹgẹ bi gomina ipinlẹ ọhun funra rẹ, Dapọ Abiọdun, ṣe wa nikalẹ.
“Ninu akitiyan lati yi awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu wọn lọkan pada lati dibo fun un lakooko ibo abẹle, lo mu ko fitan balẹ lori bo ṣe lo ọgbọn ori, ẹsẹ ati gbogbo ipa rẹ lati ran awọn eeyan lọwọ, yala lẹgbẹlẹgbẹ ni tabi eeyan kan ṣoṣo, lati le de ibi ti wọn fẹ, ati lati ri ẹsẹ mulẹ ninu oṣelu.
“Gbogbo awọn akawe ti Aṣiwaju ṣe yii ni ko pamọ fawọn eniyan. Nnkan ti n wọn ti kọ, ti wọn si ti n gbeyẹwo ninu iroyin lati bii ọdun mẹjọ sẹyin ni. Fun idi eyi, ọrọ ti ko jẹ tuntun fawọn araalu ni”.
‘‘Awọn alatako ninu ẹgbẹ oṣelu APC lo yi ọrọ gomina tẹlẹri nipinlẹ Eko ọhun pada, ki wọn baa le yi i lagbo da sina ninu ibo abẹle to n bọ.
“Nigba ti awa naa ti mọ pe, gbogbo yiyi ti wọn n yi eto ati ọjọ idibo pada le fa kikoni laya soke, awọn igbimọ eleto ipolongo yii gbagbọ pe, nnkan kan nipa Aṣiwaju ni pe, ipa pataki to ko ninu ikojọpọ ati aṣeyọri ẹgbẹ APC yoo gbe e gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ APC tọkantọkan to fẹẹ dipo aṣiwaju mu.’’
O fi kun un pe ohun ti Buhari duro le lori fun mimu ẹni ti yoo dupo aarẹ ninu ẹgbẹ wọn lo mu ki Tinubu maa tiraka bẹẹ lati le yi ọkan awọn eeyan pada, ki wọn le mọ pe oun kaju ẹ.
“Iyalẹnu lo waa jẹ fun wa pẹlu bi awọn alatako atawọn ti wọn n ba Tinubu jẹ ṣe yi ọrọ rẹ pada si ohun ti ko ro lọkan rara, tabi sọ jade lẹnu.
Tinubu o si figba kan huwa ẹlẹyamẹya tabi ko yẹpẹrẹ ẹya kankan. Iyẹn ki i tilẹ ẹ ṣe iwa rẹ rara, gẹgẹ bi Onimọ ẹrọ David Babachir Lawal ṣe n gbe e kiri lori ẹrọ alatagba Wasaapu.
“Ọrọ ti Tinubu sọ l’Abẹokuta o jọ pe o n ri Aarẹ Buhari fin, tori ẹni to mu ni pataki ni, ẹni to jẹ pe o wa ipolongo ibo Buhari ẹlẹẹkeji mọri kankan lọdun 2019 ni.
“Niwọn igba to jẹ pe fidio ọrọ to sọ lede Yoruba ọhun ti wọ ori ẹrọ ayelujara bayii, oriṣiiriṣii itumọ ni wọn n fun un, ni nnkan to si jẹ pe nitori Gomina Dapọ Abiọdun ni, eyi lo si mu ko tẹriba fun un lẹyin ọrọ ranpẹ to sọ ọhun lati ṣafihan aṣa Yoruba.
Ko ya awọn igbimọ eleto ipolongo Tinubu lẹnu nigba ti awọn alatako ninu ẹgbẹ APC yi ọrọ ohun pada si omi-in ati bo ṣe jẹ pe oun yii nikan naa ni wọn dojule.
“Igbimọ eleto ipolongo yii wa n rọ awọn oniroyin lati dakun yẹra fun awọn afikun ọrọ, ki wọn si maa ṣe iṣẹ wọn bo ti tọ ati bo ṣe yẹ lọ ninu sisọ fawọn eeyan lati dibo fun eeyan to tọ ninu ibo pamari to n bọ lọna.