Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Igbimọ to n ri si iṣakoso ile-ẹkọ gbogboniṣe ijọba apapọ to wa niluu Ẹdẹ, ti kede pe ki ọga agba ileewe naa, Dokita John Taiwo Adekọlawọle, lọ rọọkun nile.
Wọn dibo ‘a ko nigbẹkẹle ninu rẹ mọ’ nibi ipade igbimọ ti wọn ṣe lọjọ Ẹti, Furaidee, wọn si sọ pe ko yẹ ni ipo naa mọ.
Loju-ẹsẹ naa ni wọn yan igbakeji rẹ ni ẹka iṣakoso, Ọgbẹni I. T. Adelabu, lati jẹ adele-alaga igbimọ naa.
Lati bii oṣu marun-un ṣeyin ni wahala ọkan-o-jọkan ti n ṣẹlẹ nibẹ pẹlu oniruuru ẹsun ti awọn olukọ atawọn akẹkọọ fi n kan Adekọlawọle.
Lara wọn wọn ni ṣiṣe owo baṣubaṣu, wọn lo fun iyawo rẹ ni igbegba lai ti i to asiko, o gba ọmọ rẹ si iṣẹ lọna aitọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.