Faith Adebọla
Igbimọ tijọba gbe kalẹ lati ṣewadii ẹsun iwa jibiti ati lilẹdi apo pọ pẹlu ọdaran, eyi ti wọn fi kan igbakeji kọmiṣanna ọlọpaa, Abba Kyari, ti sọ pe ọrọ ko ri bi wọn ṣe n pariwo ẹ, wọn lọkunrin naa ko jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an, o si ṣee ṣe kijọba kọ jalẹ lati fa a le orileede Amẹrika to n beere ẹ lọwọ.
Olobo kan to ta ileeṣẹ oniroyin ayelujara Dailygist sọ pe abajade iwadii tileeṣẹ ọlọpaa ṣe fun Abba Kyari fihan pe loootọ lo ba afurasi ọdaran to n jẹjọ ẹsun jibiti ayelujara l’Amẹrika nni, Ramon Ọlọrunwa Abass, tawọn eeyan mọ si Hushpuppi, sọrọ, ṣugbọn awọn o ri ẹri kan to fidi mulẹ pe wọn jọ lọwọn ninu iwa jibiti kan.
Olobo naa sọ pe ko si ọrọ fifi Abba Kyari ṣọwọ sorileede Amẹrika kun awọn aba ti wọn sinu abajade iwadii wọn. Wọn ni ijiya eyikeyii ti wọn ba fẹẹ fi jẹ igbakeji kọmiṣana ti wọn ti da lọwọ kọ yii, ko ni nnkan kan i ṣe pẹlu iwa jibiti rara.
Tẹ o ba gbagbe, ile-ẹjọ giga kan lorileede Amẹrika lo paṣẹ fun ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ wọn lọhun-un, FBI (Federal Bereau of Investigation) pe ki wọn lọọ mu afurasi ọdaran naa wa s’Amẹrika latari bi Hushpuppi ṣe darukọ ẹ pe o mọ nipa awọn jibiti kan toun lu, ati awọn jọ n ṣe apapin ni.
Iwe ti FBI fi ṣọwọ sijọba Naijiria pe ki wọn yọnda Abba Kyari fawọn lo mu kileeṣẹ ọlọpaa gbe igbimọ oluṣewadii kan dide, eyi ti Igbakeji Ọga agba patapata funleeṣẹ ọlọpaa, DIG Joseph Egbunnike, ṣe alaga rẹ, ti wọn si jabọ iwadii wọn fun ijọba nipari oṣu kẹjọ to kọja yii.
Amọ ṣa o, ileeṣẹ Aarẹ ati minisita feto idajọ ni yoo pinnu igbesẹ to kan lori ọrọ naa.