Faith Adebọla, Eko
Bi Gomina Babajide Sanwo-Olu ba fi mu ileri rẹ ṣẹ pe gbogbo aba ati imọran to wa ninu abajade iwadii ti igbimọ oluṣewadii lori iwakiwa awọn ọlọpaa SARS jabọ rẹ nijọba maa mu ṣẹ, afaimọ ki ọgọọrọ awọn ọlọpaa ati ṣọja to kopa ninu iṣẹlẹ ipaniyan ati ibọn yinyin to waye ni Too-geeti Lẹkki lọdun to kọja ma fiṣẹ ọba pitan laipẹ, tori igbimọ naa ti ni ki wọn gbaṣọ lọrun gbogbo wọn.
Ninu abọ iwadii ti igbimọ tijọba ipinlẹ Eko gbe kalẹ lati tuṣu desalẹ ikoko ẹsun ifiyajẹni ati titẹ ẹtọ ẹni mọlẹ tawọn araalu fi kan awọn ọlọpaa SARS tijọba ti fofin de bayii, igbimọ naa ni awọn ti ṣewadii daadaa lori iṣẹlẹ buruku to waye logunjọ, oṣu kẹwaa, ọdun 2021, eyi to fa ọpọ awuyewuye latari bi wọn ṣe lawọn ṣọja kan lọọ yinbọn pa awọn ọdọ to n fẹhonu han lalẹ ọjọ naa, ti wọn si ṣe ọpọ leṣe.
Lakọọkọ, igbimọ naa ni kijọba gbe igbesẹ ibawi lori awọn ọga ṣọja meji kan, Lt. Colonel S. O. Bello ati Major General Godwin Umelo fun iwa afojudi ti wọn si ijokoo ọhun, wọn lawọn pe wọn lati waa wi tẹnu wọn, ṣugbọn wọn kọ jalẹ, wọn o yọju, bẹẹ ọrọ iṣẹlẹ naa kan wọn gbọngbọn, wọn fẹsun kan wọn pe wọn fẹẹ doju iwadii ru ni.
Igbimọ naa tun sọ pe kijọba ja irawọ to wa lejika gbogbo awọn ṣọja to lọ sibi iwọde alẹ ọjọ iṣẹlẹ naa, ki wọn si le wọn danu lẹnu iṣẹ ọba, tabi ki wọn fiya jẹ wọn ni kootu.
Wọn ni, yatọ si Major General Omata, gbogbo awọn ṣọja ti wọn ran niṣẹ ẹru logunjọ, oṣu kẹwaa, naa ni wọn ko fi t’ọmọ jẹ ẹ, wọn jiṣẹ kọja aala, wọn o si yẹ lẹni ta a gbọdọ pe ni agbofinro rara, bẹẹ ni wọn o gbọdọ gba wọn sẹnu iṣẹ ọba kankan.
Igbimọ naa tun sọ pe kijọba yọ ọga ọlọpaa DPO teṣan Marọkọ niṣẹ bii ẹni yọ jiga, ki wọn si le gbogbo awọn ọlọpaa tọkunrin naa ko lọ si Too-geeti lasiko iṣẹlẹ naa danu, wọn ni gbogbo wọn lọwọ wọn o mọ ninu iṣẹlẹ alẹ ọjọ naa.
Igbimọ naa dupẹ wọn tọpẹ da lọwọ awọn ileewosan aladaani ti wọn gba ọgọọrọ awọn to fara pa nibi iṣẹlẹ ọhun, ti wọn si tete pese itọju iṣegun to doola ẹmi wọn fun wọn.