Igbimọ oluwadii ifiyajẹni SARS ni kawọn ọlọpaa mẹrin fara han kiakia l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Igbimọ tijọba ipinlẹ Ọṣun gbe kalẹ lati ṣewadii oniruuru ẹsun ti awọn araalu ni ta ko awọn agbofinro ti paṣẹ pe ki awọn ọlọpaa mẹrin fara han niwaju awọn, aijẹ bẹẹ, pampẹ ofin ni wọn aa fi gbe wọn.

Ninu awọn ọlọpaa mẹrin ọhun la ti ri kọmisanna funleeṣẹ ọlọpaa tẹlẹ fun ipinlẹ Ọṣun, John Moronikẹ, awọn yooku ni Inspẹkitọ Muyiwa, SP Ọmọtale ati Joshua Atuniṣe.

Alaga igbimọ naa, Adajọfẹyinti Akin Ọladimeji, ti kọkọ sọ pe lara agbara ti igbimọ naa ni ni lati paṣẹ fun ẹnikẹni ti ọrọ ba kan pe ko yọju si awọn fun awijare to ba ni lori ẹsun ti wọn ba fi kan an.

O ni pupọ iwe ẹsun to wa niwaju igbimọ naa lo ni i ṣe pẹlu iwa buruku ti awọn ọlọpaa ti hu, to si le yọri si ibanilorukọ jẹ, idi niyi to fi pọn dandan ki awọn ọlọpaa yọju lati ṣe afọmọ orukọ wọn.

Wọn ranṣẹ si Inspẹkitọ Muyiwa ati SP Ọmọyale lati waa sọ idi ti wọn fi gba owo ribiribi lọwọ olupẹjọ kan, Oloye Adanku Oyinlọla, ati idi ti wọn fi fiya jẹ ẹ lọna aitọ.

Ni ti Ọmọronikẹ ati Joshua Atunise, ẹsun tiwọn ni bi wọn ṣe tapa sofin ile-ẹjọ lati san miliọnu lọna ọgbọn naira fun idile oloogbe Babatunde, akẹkọọ Poli Ẹsa-Oke, ti wọn pa, ati bi wọn ṣe kuna lati gbe oku ọmọ naa silẹ fawọn mọlẹbi ẹ.

Leave a Reply