Igbimọ tijọba yan lori ifiyajẹni SARS bẹrẹ gbigba iwe ẹhonu l’Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Igbimọ tijọba ipinlẹ Ekiti gbe kalẹ lati gbọ ẹhonu araalu lori ifijyajẹni ikọ ọlọpaa to n gbogun ti idigunjale (SARS) tijọba apapọ ti tuka bayii ti bẹrẹ iṣẹ gbigba iwe ẹhonu lọwọ araalu.

Igbimọ ọhun ni Gomina Kayọde Fayẹmi ṣefilọlẹ lopin ọsẹ to kọja lati ṣewadii ijinlẹ lori ifiyajeni to waye latọwọ awọn SARS, awọn ọlọpaa lapapọ ati iru iṣẹlẹ bẹẹ to waye lasiko iwọde tawọn araalu ṣe fun bii ọsẹ meji.

Igbimọ ẹlẹni-mẹwaa ọhun ti wọn pe ni ‘’Ekiti State Judicial Panel of Inquiry into Allegations of Human Rights Violations against Police Officers including officers of the Special Anti- Robbery Squad (SARS) and other Persons’’ ni Onidaajọ Cornelius Akintayọ to jẹ adajọ-fẹyinti jẹ alaga fun, nigba tawọn mẹsan-an to ku jẹ ọga ọlọpaa to ti fẹyinti, amofin, ajafẹtọọ-ọmọniyan, oniroyin ati aṣoju ọdọ.

Iṣẹ ti wọn gba ni gbigba iwe ẹhonu lori ifiyajẹni ati ipaniyan lọna aitọ, ati iṣẹlẹ biba dukia ẹni jẹ, bẹẹ ni ki wọn ṣewadii ijinlẹ, ki wọn si ṣeto bi awọn tiya jẹ yoo fi ri owo gba-ma-binu.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Nitori obinrin, Danladi gun ọrẹ rẹ pa l’Ode-Aye

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ Ọkunrin ẹni ọdun mejilelogun kan, Money Danladi, ni wọn ti fẹsun kan …

Leave a Reply

//zeechumy.com/4/4998019
%d bloggers like this: