Igbimọ to n ṣewadii ẹsun awọn ti SARS fiya jẹ pari ijokoo wọn lẹyin ọdun kan

Faith Adebọla, Eko

 Lẹyin ọdun kan gbako ti wọn ti n gbọ oriṣiiriṣii ẹsun, ti wọn si ti n rọ awọn eeyan lọkan pẹlu ẹbun owo ‘gba-ma-binu,’ igbimọ tijọba Eko gbe kalẹ lati wadii ẹsun lori awọn ti ọlọpaa ati ikọ ọlọpaa SARS ti wọn ti wọgi le bayii fiya jẹ, ti pari iṣẹ wọn, wọn si ti fopin si ijokoo wọn.

Alaga igbimọ naa, Adajọ Doris Okuwobi, sọ pe iṣẹ kan ṣoṣo to kẹyin tawọn n ṣe ni abọ iwadii lori iṣẹlẹ iwọde EndSARS to ṣẹlẹ logunjọ, oṣu kẹwaa, ọdun 2020, nibi ti wọn ti fẹsun kan awọn ṣọja ati ọlọpaa pe wọn yinbọn pa diẹ lara awọn oluwọde ọhun lalẹ ọjọ naa ni Too-geeti Lẹkki, wọn si ṣe awọn mi-in leṣe lara wọn.

O lawọn ti pari akọsilẹ iwadii awọn, gbogbo awọn ẹri tawọn ri lawọn yoo fi ṣọwọ sijọba lẹkun-unrẹrẹ. O ni gbogbo ẹtọ ati ẹbun to ba yẹ kijọba san fawọn ti ọrọ naa kan lawọn yoo jẹ kijọba mọ bo ṣe tọ, paapaa lori ti iṣẹlẹ to waye ni Too-geeti Lẹkki lalẹ ọjọ naa.

O lawọn iwe ẹsun ti ko ṣee ṣe fun igbimọ naa lati ṣiṣẹ le lori lawọn yoo taari si ẹka eto idajọ tipinlẹ Eko lati yan awọn to maa mojuto o.

Adajọ naa sọ pe aropọ iwe ẹsun ojilerugba o din marun-un (235) lawọn gba laarin oṣu meji pere, iyẹn oṣu kẹwaa, ọdun 2020, ti wọn ṣefilọlẹ igbimọ ọhun si oṣu kejila, ọdun naa, mẹrinla ninu ẹsun ọhun lo da lori iṣẹlẹ ti Lẹkki Too-geeti yii.

Ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹwaa, ọdun to kọja, ni wọn ṣedasilẹ igbimọ yii, latari ipinnu ijọba apapọ to paṣẹ pe kawọn ipinlẹ lọọ ṣewadii lori ẹsun awọn tọlọpaa ti fiya jẹ lọna aitọ sẹyin, ki wọn si damọran ipẹtu-saawọ to ba yẹ fun wọn, ati ijiya to yẹ fawọn ọlọpaa to jẹbi.

Leave a Reply